Ọwọ ti tẹ awọn janduku to ṣeku pa Ọba Olufọn l’Ondo

Aderounmu Kazeem

Ni bayii, ọwọ ti tẹ awọn janduku kan ti wọn sọ pe o ṣee ṣe ki wọn mọ nipa bi wọn ṣe pa Ọba Israel Adewusi, Olufọn ti ilu Ifọn, nipinlẹ Ondo laipẹ yii.

Ninu ọrọ Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ọga awọn Amọtẹkun, o ni ninu igbo kan ni Ẹlẹgbẹka nipinlẹ Ondo lọwọ ti tẹ wọn, ati pe awọn ko ti i fẹẹ darukọ wọn, ko ma ba a ṣakoba fun iwadii awọn.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja ni Ọba Adeusi doloogbe nigba tawọn janduku ajinigbe kan kọlu u laarin Ẹlẹgbẹka si ilu Ifọn, lasiko to n ti ibi ìpàdé kan niluu Akurẹ bọ.

Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ọga awọn Amọtẹkun ti wọn mu awọn ẹni-afurasi yii nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Akurẹ, sọ pe eeyan mẹrin tawọn ajinigbe yii ko pamọ lawọn ti gba silẹ bayii nibi tawọn ti n wa awọn eeyan to ṣeku pa Ọba Adeusi.

O fi kun un pe awọn ti bẹrẹ sí fọrọ wa awọn ẹni afurasi tọwọ tẹ ọhun lẹnu wò lati mọ bi ọrọ iku Ọba Ifọn ṣe jẹ gan-an.

Bakan naa lo fidi ẹ mulẹ pe ogun eeyan lọwọ ti tẹ bayii lawọn ibi kọlọfin kọọkan niluu Akurẹ atawọn agbegbe ẹ, ati pe lara awọn eeyan tawọn mu ọhun lasiko ti wọn n ṣiṣẹ ibi lọwọ ni ọwọ tẹ wọn.

 

Leave a Reply