Ọwọ ti tẹ marun-un ninu awọn to pa akẹkọọ Fasiti Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ajọ ẹsọ alaabo (DSS), ẹka ti ipinlẹ Kwara ti mu awọn afurasi marun-un, ti wọn fipa ba Ọlajide Blessing, akẹkọọ Fasiti Ilọrin lo pọ, ti wọn tun seku pa a.

A oo ranti pe ni nnkan bii ọṣẹ meji ṣẹyin ni awọn janduku afurasi naa ya bo ile ti Blessing n gbe ni agbegbe Tanke, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti wọn si fi tipa ba a lo pọ, ti wọn tun ṣeku pa a.

Oloogbe ọhun jẹ akẹkọọ Fasiti Ilọrin, ni ẹka eto ọgbin, to si wa ni ọdun kẹta (300 Level) nileewe naa.

Ajọ ẹsọ alaabo ọhun sọ pe ọna mẹrin ọtọọtọ lawọn ti mu awọn eeyan naa niluu Ilọrin. Wọn ni ẹkunrẹrẹ iwadii n tẹsiwaju.

Leave a Reply

//eephaush.com/4/4998019
%d bloggers like this: