Ọwọ ti tẹ mẹta ninu awọn to ji alaga kansu Iganna gbe

Kazeem Aderohunmu

Gomina Ṣeyi Makinde ti gboriyin fun ileeṣẹ ọlọpaa lori bi wọn ti ṣe mu awọn mẹta ti wọn sọ pe wọn mọ si bi wọn ṣe ji alaga kansu ijọba ibilẹ idagbasoke Iganna, nipinlẹ Ọyọ, gbe.

Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni iroyin gba igboro pe wọn ti ji Ọgbẹni Jacob Adeleke, ẹni ti i ṣe alaga ijọba Iganna gbe, ti wọn si pada ri i lẹyin to ti lo bii ọjọ marun-un lọdọ wọn.

Oun ati derẹba ẹ to n jẹ Mufu ni wọn jọ ji gbe, ti wọn si ti pada tu wọn silẹ leyin ti wọn gba aimọye miliọnu naira lọwọ wọn.

Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ti i sọ pato bi ọwọ ṣe tẹ wọn, sibẹ, Gomina Makinde ti dupẹ lọwọ wọn lori iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe ọhun.

 

Leave a Reply