Ọwọ ti tẹ Tina, ọmọ lanledi to lu tẹnanti wọn pa tori owo ina n’Ikorodu

Faith Adebọla, Eko

Ahamọ ọlọpaa ni ọmọbinrin kan, Tina Essi, wa bayii latari bi wọn ṣe lo fija pẹẹta pẹlu mama ẹni ọdun mọkandinlaaadọta kan, Christiana Akparie, to jẹ ọkan lara awọn ayalegbe mama ẹ, lo ba lu mama onimama pa.

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu atẹjade kan ti Olumuyiwa Adejọbi, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, fi ṣọwọ s’ALAROYE, wọn ni iwadii awọn ọlọpaa fihan pe ọrọ owo ina ẹlẹntiriiki ti wọn maa n pin san nile wọn to wa ni Ojule kẹrindinlọgbọn, Opopona Orijamogun, laduugbo Ọrẹyọ, n’Ikorodu, l’Ekoo, lo da wahala silẹ laarin afurasi ọdaran yii ati oloogbe naa.

Ọjọ Aiku, Sannde, to kọja lọhun-un ni wọn lọrọ ija ọhun ti kọkọ waye latari bi tẹnanti oloogbe yii ṣe ṣaroye pe ojooro wa ninu bi wọn ṣe n pin owo ina naa ati bi wọn ṣe n gba a, o ni aparo kan ko ga ju ọkan lọ lo yẹ ki wọn fọrọ owo ina naa ṣe, bẹẹ ile kan naa yii loun atọmọ tiyaa rẹ kọle ọhun jọ n gbe.

Wọn ni ọrọ yii ni wọn fa, ti wọn sọ ọ di ran-n-to mọra wọn lọwọ, nija ba bẹ silẹ laarin Tina ati Christiana, awọn mejeeji si wọya ija. Ṣugbọn Tina ṣi san-an-gun daadaa, wọn lo lu mama naa lalubami, kawọn alajọgbele atawọn aladuugbo to ku too le la wọn.

Wọn ni latọjọ naa ni oloogbe yii ti n lọgun pe ara n ro oun, wọn ti kọkọ gbe e lọ sọsibitu, wọn tun da a pada wale, o si n lo oogun aparora lojoojumọ, ṣugbọn irora ta ku, ko lọ. Laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, ni wọn tun fẹẹ gbe mama naa lọ sọsibitu Jẹnẹra Ikorodu pe ki wọn tun ba wọn wo o, ṣugbọn wọn loju ọna ni wọn wa ti mama naa fi dakẹ, lo ba ṣe bẹẹ dagbere faye.

Igba tọrọ si ti ja siku, awọn aladuugbo ko le sin in lokuu oru mọ, ni wọn ba fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa tẹsan Ikorodu leti, ṣugbọn kawọn ọlọpaa too de, afurasi ọdaran yii ti fẹsẹ fẹ ẹ, lo ba di pe wọn bẹrẹ si i wa a, ko si pẹ tọwọ fi ba a lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Akata awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, lo wa bayii, ibẹ lo ti n dahun awọn ibeere ti wọn n bi i, o si ti n ṣalaye ara ẹ fun wọn.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu, lawọn ti n to iwe ẹsun ẹ jọ, gbara ti iwadii ba ti pari lawọn maa tete taari ẹ siwaju adajọ, ko le lọọ ṣalaye bi ẹmi iya oniyaa to yale gbe lọwọ mọmi ẹ ṣe tọwọ ẹ bọ.

Leave a Reply