Ọwọ ti tẹ Toyin, ijaabu loun ati ọkọ rẹ fi n lu awọn aafaa ni jibiti l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Tọkọ-taya kan ti wọn n fi ẹṣin Musulumi boju lu awọn eeyan ni jibiti lọwọ palaba wọn ti ṣegi pẹlu bọwọ ajọ sifu difẹnsi ṣe tẹ wọn niluu Irẹṣẹ, nijọba ibilẹ Ifẹdọrẹ, nibi ti wọn fi ṣe ibuba.

Awọn afurasi ọhun, Oluwaṣeun Toyin, Quazeem Ismail, ọkọ rẹ, ati ọmọbinrin kan, Tosin Michael, lọwọ tẹ lọsẹ yii lẹyin ti wọn ti lu ọpọlọpọ awọn eeyan ni jìbìtì niluu Akurẹ ati agbegbe rẹ.

Ni ibamu pẹlu alaye ti alakooso awọn sifu difẹnsi ipinlẹ Ondo, Dokita Hammed Abọdunrin, ṣe fawọn oniroyin lasiko ti wọn n ṣafihan awọn afurasi ọdaran ọhun ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Alagbaka, l’Akurẹ.

O ni ṣe ni Toyin ati ọkọ rẹ jọ gbimọ-pọ, ti wọn si lọọ ran ijaabu kan ti ọmọbinrin ẹni ọdun mejilelọgbọn ọhun si n fara rẹ han gẹgẹ bii Musulumi ododo nigbakuugba ti wọn ba ti fẹẹ lọọ ṣiṣẹ gbaju-ẹ ti wọn yan laayo.

Awọn mọsalasi ni tọkọ-taya naa saaba maa n lọ, irọ ti wọn si maa n pa fawọn aafaa atawọn olujọsin ti wọn ba ti ba lawọn ile-ijọsin ọhun ni pe ọmọlẹyin Krisiti ni Toyin pẹlu aburo rẹ tẹlẹ, ati pe ni kete toun ati Tosin aburo rẹ ti gba ẹṣin Musulumi lawọn ẹbi ti kẹyin si wọn, ti wọn si le e kuro nile ti wọn n gbe l’Ekoo

Ọpọlọpọ igba ní Toyin maa n yi orukọ rẹ pada tí yoo si ni Sulifa tabi Zainab loun n jẹ, ti Tosin aburo rẹ naa si n pe ara rẹ ni Sadiat, kawọn ti wọn fẹẹ lu ni jibiti le gba wọn gbọ pe Musulumi ododo ni wọn loootọ.

Quazeem ni wọn lo maa n fi ọkada gbe wọn kaakiri ọdọ awọn aafaa ati mọṣalasi nibi tawọn eeyan ti n da ọpọlọpọ owo jọ fun wọn.

Awọn afurasi mẹtẹẹta lọwọ tẹ ni ibẹrẹ ọsẹ ta a wa yii lasiko ti wọn tun n lu awọn eeyan ni jibiti lọwọ gẹgẹ bii iṣe wọn, ti awọn eeyan sì fa wọn le awọn sifu difẹnsi lọwọ.

Dokita Abọdunrin ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi onijibiti ọhun.

 

Leave a Reply