Ọwọ wa ti tẹ awọn afurasi kan lori akọlu to waye ni ṣọọsi Ọwọ-Adelẹyẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn afurasi kan to ṣee ṣe ki wọn mọ nipa iṣẹlẹ akọlu to waye ninu sọọsi Katoliiki Francis Mimọ tilu Ọwọ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa yii, lọwọ ti tẹ, ti wọn si ti wa nikaawọ ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo lọwọlọwọ.

Alakooso ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, lo fidi ọrọ naa mulẹ lasiko to n ṣe afihan awọn afurasi ọdaran kan ni olu ileeṣẹ wọn tó wa lagbegbe Alagbaka, niluu Akurẹ, laaarọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Adelẹyẹ ni lati igba ti iṣẹlẹ buruku naa ti waye lawọn ko ti sinmi pẹlu bi awọn ṣe fọn sinu awọn aginju to wa layiika Ọwọ lati ṣawari awọn ọdaju ọdaran ọhun lọnakọna.

O ni ki iṣẹlẹ aburu ọhun too waye lawọn ẹṣọ alaabo kan ti ta awọn lolobo pe awọn amookunsika kan n gbero lati ṣiṣẹ ibi, leyii to mu kawọn ẹṣọ alaabo to le lọgọrun-un, ninu eyi ta a ti ri, ẹsọ Amọtẹkun atawọn ṣọja fọn sinu igbo lati ṣawari awọn agbesunmọmi ọhun ki wọn too mu erongba wọn ṣẹ.
O ni lẹyin ti awọn ti wa ninu aginju Ondo ati Edo fun bii ọsẹ kan gbako lai kofiri ohunkohun lawọn ṣẹṣẹ kuro, nireti pe awọn to fẹẹ ṣiṣẹ ibi naa ti ba ẹsẹ wọn sọ̀rọ̀.

Oloye Adelẹyẹ ni idaji ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ ti akọlu ọhun waye lawọn kuro ninu igbo, toun si paṣẹ fawọn ọmọlẹyin oun ki okukuluku wọn pada si aaye wọn.

O ni kayeefi patapata lo jẹ foun nigba ti oun tun gba ipe lati ọdọ awọn oṣiṣẹ Amọtẹkun ẹka tilu Ọwọ pe wọn tun tí ji awọn eeyan kan gbe laimọ pe ṣe ni wọn kan fẹẹ lo iroyin naa lati tan awọn kuro laarin ilu, ki wọn le raaye ṣiṣẹ ibi wọn.

Ni kete ti wọn gbọ nipa akọlu ọhun lo ni awọn ti sare ko ara awọn jọ, ti awọn si lepa wọn titi ti wọn fi gbe ọkọ wọn ju silẹ, ti wọn sa wọnu igbo lọ.
Asiko ti wọn n tọpasẹ awọn ọdaran yii lo ni wọn ṣeku pa ọkan ninu awọn ẹṣọ Amọtẹkun to n lepa wọn.
O ni loootọ lọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi kan ti wọn mọ nipa ọrọ akọlu naa, ṣugbọn ko ti i to asiko ti awọn fẹẹ foju wọn lede tabi ki wọn ba awọn oniroyin sọrọ, nitori iwadii to si n lọ lọwọ.

Oludamọran agba fun gomina lori eto aabo ọhun ni awọn ṣi n tẹsiwaju lati maa lepa awọn agbebọn naa titi tọwọ ofin yoo fi tẹ gbogbo wọn atawọn to bẹ wọn lọwẹ laipẹ.
O ni awọn ti ba iwadii awọn de ibi kan, leyii to ran awọn lọwọ lati mọ ibi ti wọn gba wọle ati ọna ti wọn gba sa lọ.
Apapọ awọn afurasi ọdaran ti wọn ṣe afihan wọn lọjọ naa jẹ mọkanlelaaadọrin (71) ninu eyi ta a ti ri awọn ajijigbe, adigunjale, ọmọ ẹgbẹ okunkun, awọn ole a-ji-ọkada atawọn ẹsun ọdaran mi-in.
Awọn afurasi ọhun lo ni awọn ri mu lawọn ilu bii Ọwọ, Supare Akoko, Akurẹ atawọn ilu mi-in nipinlẹ Ondo.

Leave a Reply