Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ni awọn afurasi janduku bii mẹẹẹdogun lo ti wa ni ikawọ awọn latari rogbodiyan to su yọ lasiko iwọde SARS to waye l’Akurẹ ati agbegbe rẹ.
Alukoro wọn, Tee-Leo Ikoro, to fidi ọrọ yii mulẹ ni gbogbo awọn tọwọ tẹ naa ni wọn lọwọ si ọkan-o-jọkan awọn ẹru ti wọn ji ko atawọn dukia to ṣofo lasiko iwọde ti wọn ṣe naa.
Iwọde SARS yii lo ni awọn janduku ọhun fi boju ti wọn fi lọọ digunjale lagbegbe Sijuade, l’Akurẹ, nibi ti wọn ti yinbọn pa ọkunrin oniṣowo kan lopin ọsẹ to kọja.
Bẹẹ lo ni ko si ojulowo awọn oluwọde SARS ninu gbogbo awọn ti wọn mu naa.
Ikoro ni iwadii si n tẹsiwaju lori bi wọn ṣe fẹẹ ri iyoku awọn janduku ọhun mu laipẹ.