Ọwọ yẹpẹrẹ nijọba Buhari fi mu eto aabo lorileede yii- Awọn gomina ẹgbẹ PDP tẹlẹ

Faith Adebọla

Pẹlu bi orileede wa ṣe n koju ipenija eto aabo bayii, agbarijọ awọn gomina tẹlẹ ri labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ti ṣepade l’Abuja, wọn ni Aarẹ Muhammadu Buhari ti kuna lati pese aabo to peye fawọn ọmọ orileede yii, o si di dandan kawọn ṣe nnkan kan nipa iṣoro naa ni kiamọsa.

Ipade naa, eyi to waye lọjọ Ẹti, Furaidee yii, ni Legacy House, to wa lọna Shehu Shagari, lagbegbe Maitama, l’Abuja, ni ọpọ awọn gomina ana lẹgbẹ oṣẹlu PDP pesẹ si.

Gomina ipinlẹ Niger tẹlẹ, Alaaji Babangida Aliyu, lo ṣe alaga ipade ọhun.

Atẹjade kan ti wọn fi lede lẹyin ipade yii, eyi ti Ọgbẹni Bala Bitrus, alakooso eto iroyin fun Babangida Aliyu, buwọ lu lorukọ ọga rẹ ati ẹgbẹ awọn gomina naa sọ pe awọn ti ṣakiyesi pe ọwọ dẹngẹrẹ ni ijọba Buhari fi mu eto aabo lorileede yii, eyi si ti ṣakoba gidi debii pe pẹlu ibẹru bojo lawọn eeyan n sun kaakiri origun mẹrẹẹrin orileede yii, ko si sẹni tọkan rẹ balẹ labẹ orule rẹ mọ.

Atẹjade naa ka lapa kan pe:

“Ẹgbẹ awa gomina ana ti PDP ti foju ṣunnukun wo bi nnkan ṣe n bajẹ balumọ lorileede yii, ati bi aabo lori ẹmi ati dukia ṣe n poora lọ, ti iṣọkan si ti sọnu laarin awọn araalu nilẹ wa.

A ti ri i pe ipenija yii ko da ibi kan si, kaakiri origun mẹrẹẹrin Naijiria ni iṣoro naa ti n ba awọn eeyan finra.

A tun ti kiyesi bi iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe gbọjẹgẹ lori iṣoro eto aabo yii, ti nnkan naa si n buru si i bọjọ ṣe n gori ọjọ.

“Latari eyi, a rọ gbogbo awọn to ti ṣe gomina ri nilẹ yii, lai fi ti ẹgbẹ oṣelu yoowu ti wọn wa nigba yẹn ati lasiko yii ṣe, ki wọn jẹ ka jọ fori kori lori ipenija yii, ka si mọ bi a oo ṣe da orileede yii pada lẹnu ọgbun nla to fẹẹ ko si yii.

“A gboṣuba fun ẹgbẹ oṣelu PDP lori akitiyan wọn lati pari gbogbo aawọ ati aigbọra-ẹni-ye to wa laarin ẹgbẹ naa, iṣẹ gidi ni igbimọ apẹtusaawọ naa n ṣe, a si mọyi aṣeyọri ti wọn ti ṣe.

“A rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ PDP nile-loko lati ni ẹmi idariji, ifẹ, alaafia, amumọra ati ifarada fẹni ki-in-ni keji wọn.

“A ṣeleri lati tubọ ronu jinlẹ pẹlu awọn ẹlẹgbẹ wa to ku lati wa ọna abayọ si ipenija to n koju Naijiria yii, ka si bọ lọwọ ewu.”

Lara awọn gomina ana to pesẹ peju sipade naa ni Alaaji Idris Wada lati Kogi, Ahmed AbdulFatah lati Kwara, Emeka Ihedioha lati Imo, Rabiu Kwankwaso lati Kano, Sule Lamido lati Jigawa, Peter Obi lati Anambra, Liyel Imoke lati Cross River, Ibrahim Shema lati Katsina ati awọn mi-in.

Leave a Reply