Monisọla Saka
Ọrọ buruku toun tẹrin ni ọrọ awọn mọlẹbi oloogbe kan nipinlẹ Anambra, ti wọn gbe maṣinni pelebe ti wọn fi n gbowo, POS, sori tebu, wọn ni ki awọn ti wọn waa ba wọn kẹdun eeyan wọn to ku le ribi fun wọn lowo. Eleyii ki i ṣe ijokoo alaafaa tabi awọn pasitọ Kankan o. Eto isinku ni wọn n ṣe, funra awọn mọlẹbi ni wọn si sọ ọ di mimọ fawọn eeyan to wa nikalẹ nibẹ.
Lasiko ti eto isinku baba wọn agba ọhun n lọ lọwọ lawọn mọlẹbi ti kede pe awọn o fẹ owo atijọ, ki awọn ti ko ba si ni owo tuntun lọwọ mu kaadi ATM wọn lati fi sanwo ti wọn ba fẹẹ fun awọn. Wọn ni ko si awijare fẹnikẹni lati ma ṣe fi owo silẹ, ki ẹni ti ko ba lowo tuntun ṣe tiransifaa, abi ki wọn fi POS sanwo. Bakan naa ni wọn tun kọ nọmba akaunti, nitori awọn ti ATM wọn ko ba si pẹlu wọn, ṣugbọn ti wọn le fowo ṣọwọ si wọn lati ori foonu wọn.
Pẹlu ede Ibo wọn yii naa ni ọkunrin kan ninu ẹbi ti dupẹ lọwọ awọn eeyan fun bi wọn ṣe yẹ wọn si, lẹyin naa lo rọ wọn pe, “latari bi orilẹ-ede yii ṣe ri bayii, ti ijọba si n kede owo-ina ori ẹrọ ayelujara ti ko ni i ṣe pẹlu owo beba, a ti ṣeto ẹrọ POS ati akaunti banki fun awọn ti ko ba ni owo tuntun lọwọ. Ẹ lọ si awọn ori tebu kaakiri, ẹ o ri POS nibẹ, ẹni ko ba si ni kaadi ATM lọwọ, akaunti nọmba la kọ sibi beba nla ta a so kọ yẹn. Mo lero pe ọrọ mi ye wa? Ẹ ṣee o.
Eyi waye latari bi ijọba apapọ ṣe kede pe ẹẹdẹgbẹta (500) ati ẹgbẹrun (1,000) Naira ti di kọndẹ, ko ni i jẹ nina mọ, ki awọn ti wọn ba ni in lọwọ si ko o lọ si banki apapọ ipinlẹ wọn, lẹyin ti wọn ba ti tẹle alakalẹ eto ti banki apapọ fun wọn.
Ninu fidio ti wọn gbe sori ẹrọ ayelujara yii, bii ọna mẹta ti wọn gbe tebu kalẹ si ni wọn ko maṣinni POS meji meji si, awọn ti wọn jokoo sibẹ lati da awọn eeyan lohun si jokoo ti i gbaagbaagba bii ẹni pe wọn wa nidii ọja wọn ni. Owo perete lo wa ninu tiree nla kan ti wọn gbe kalẹ lati maa fi gbowo, o jọ pe inu apo banki ọhun ni pupọ eeyan n sanwo si, nigba ti ko ti si owo rẹpẹtẹ niluu.
Niwaju tebu kọọkan yii naa ni wọn tun so beba fẹrẹgẹdẹ kan si, orukọ, nọmba ati iru banki ti wọn maa fowo ranṣẹ si, ni wọn kọ sibẹ, wọn si gbe okuta le e nitori ki atẹgun ma baa gbe e lọ. Niwaju fọto baba to ku yii bakan naa, wọn tun gbe awo ijẹun kekere aye atijọ kan sibẹ, fun anfaani awọn ti wọn ba fẹẹ sọ owo sibẹ.