Oyebamiji lo wọle ibo Ekiti, ṣugbọn Ṣẹgun Oni loun ko ni i gba

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Lẹyin ti ajọ eleto idibo ti kede oludije lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC, Biọdun Oyebamiji gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo to waye ni Satide, ọjọ Abamẹta. ọsẹ to kọja yii, ẹni to ṣe ipo keji ninu eto idibo naa lati inu ẹgbẹ SPD, Ṣẹgun Oni. ti ni oun ko gba abajade esi idibo naa wọle.
Nigba to n sọrọ lati ẹnu Akọwe iroyin rẹ, Moses Jọlayẹmi, ti ni ojooro ati fifi owo ra ibo lo gbode kan lasiko ti eto idibo naa waye. Bakan naa lo ni awọn agbofinro kun awọn ẹgbẹ alatako yii lọwọ lati ṣe eru lasiko idibo ọhun.
O ni awọn ko gba esi idibo naa wọle, lẹyin tawọn ba ṣepade lati ṣe agbeyẹwo esi idibo naa lawọn maa ṣepade lori igbesẹ to kan lati gbe lori ọrọ naa.
Aarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni ajọ eleto idibo ipinlẹ Ekiti kede Abiọdun Oyebamiji gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori lasiko eto idibo naa. Ibo ẹgbẹrun lọna aadọwaa n o din mẹta (187, 052 )ni oludije ẹgbẹ oṣelu APC yii ni. Nigba ti Ṣẹgun Oni to jẹ ọmọ ẹgbẹ SDP ni ibo ẹgbẹrun mejilelọgọrin ati diẹ (82, 211). Ọmọ ẹgbẹ PDP to ṣe ipo kẹta ni ibo ẹgbẹrun mẹtadinlaaadọrin ati diẹ (67, 457).
Eyi lo jẹ ki wọn kede Oyebamiji o ni ibo to pọ ju gẹgẹ bii ẹni to bori eto idibo naa.
Oyebamiji ti wọn dibo yan naa ti dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ekiti pẹlu bi ọn ṣe fibo wọn gbe e wọle.

Leave a Reply