Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ni ọsan ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni Adajọ agba nipinlẹ Ekiti, Oyewọle Adeyẹye, ṣebura fun gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ekiti, Abiọdun Oyebanji ati Igbakeji rẹ, Monisade Afuyẹ ni Ekiti Parapọ Pavillion, to wa niluu naa.
Kaakiri origun mẹrẹẹrin Naijiria ati yika ipinlẹ Ekiti ni awọn eeyan ti waa ba gomina tuntun naa dawọọ idunnu iyansipo rẹ ọhun.
Ni nnkan bii aago kan ku diẹ ni ayẹyẹ ibura naa waye fun Gomina Oyebanji, ti wọn si ko kọkọrọ isakoso le e lọwọ gẹgẹ bii gomina keje nipinlẹ naa.
Lara awọn eeyan pataki atawọn oloṣelu to wa nibẹ ni gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe, Oloye Bisi Akande, oludije funpo aarẹ lẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, bakan naa ni Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki.