Oyetọla ṣagbekalẹ igbimọ ti yoo maa mojuto ikọ Amọtẹkun l’Ọṣun

 Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti ṣagbekalẹ ikọ ẹlẹni-mẹẹẹdogun ti yoo maa mojuto igbokegbodo ikọ Amọtẹkun nipinlẹ naa. Ninu ọfiisi gomina leto naa ti waye nirọlẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii. Oyetọla ṣalaye pe igbimọ ikọ Amọtẹkun, eleyii ti Ajagun-fẹyinti Ademọla Aderibigbe yoo jẹ alaga fun ni yoo maa dari iṣọwọṣiṣẹ awọn ikọ naa.

O ni gbogbo ipa niṣejọba oun n sa lati ri i pe ko si ẹlẹgbẹ ipinlẹ Ọṣun ninu ipinlẹ to ni alaafia ju lọ, ti eto aabo rẹ si dangajia lorileede yii.

O ṣalaye pe nigba ti wahala eto aabo pọ ju, gbogbo awọn ipinlẹ Yoruba finu konu, wọn wa ọna abayọ nipasẹ idasilẹ Amọtẹkun, ko too di pe nnkan yoo bọ sori, o si daju kedere pe ikọ naa ko ni i ja awọn araalu kulẹ.

Oyetọla fi kun ọrọ rẹ pe awọn ajagun-fẹyinti meji ni wọn wa lara awọn igbimọ Amọtẹkun toun ṣagbekalẹ rẹ ọhun, oun si mọ pe ọgbọn ati iriri wọn lẹnu iṣẹ ologun yoo ran ikọ naa lọwọ pupọ.

Gomina waa rọ awọn igbimọ naa, ninu eyi ti kabiesi mẹta wa, lati ṣiṣẹ takuntakun fun eto aabo ipinlẹ Ọṣun, o ni awọn araalu nigbagbọ kikun ninu wọn, wọn ko si gbọdọ ja wọn kulẹ.

Yatọ si awọn igbimọ ikọ Amọtẹkun, Oyetọla tun ṣagbekalẹ igbimọ ẹlẹni-mẹta ti yoo maa gbọ awuyewuye awọn araalu nipa Amọtẹkun (The Amotekun Independent Complaints Board), o si fi Onidaajọ Moshood Adeigbe to ti fẹyinti ṣe alaga rẹ.

Ninu ọrọ tirẹ, Ajagun-fẹyinti Aderibigbe ṣeleri lorukọ awọn ọmọ igbimọ ikọ Amọtẹkun lati ṣiṣẹ naa de oju-ami lai bẹru ẹnikẹni.  Bakan naa ni Ọrangun ti Oke-Ila, Ọba Abọlarin, gboriyin fun Gomina Oyetọla fun bo ṣe ri i daju pe awọn ori-ade wa lara awọn ọmọ igbimọ naa, o ni eleyii yoo ni ipa rere lori iṣọwọ-ṣiṣẹ ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun.

Leave a Reply