Oyetọla, Adeoti ati Lasun fara han niwaju igbimọ ti yoo ṣeto idibo abẹle l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn oludije mẹtẹẹta ti wọn fẹẹ kopa ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, ni wọn jokoo papọ l’ọjọ Ẹti, Furaidee, nibi ipade ti igbimọ ti yoo ṣakoso idibo naa pe si sẹkiteriati ẹgbẹ wọn niluu Oṣogbo, nirọlẹ ọjọ Ẹti.

Awọn oludije mẹtẹẹta naa ni Gomina Gboyega Oyetọla, Alhaji Moshood Adeoti ati Ọnarebu Lasun Yusuf.

Nibi ipade naa ni alaga igbimọ ọhun, to tun jẹ gomina ipinlẹ Kwara, Alhaji Abdulrasaq Abdulrahman ti sọ pe gbogbo ọmọ ẹgbẹ to ba ni kaadi ni yoo kopa ni gbogbo wọọdu ojilelọọọdunrun o din mẹjọ to wa l’Ọṣun.

O ṣalaye pe aago mẹjọ aarọ si aago mejila ni iforukọsilẹ yoo waye, lẹyin naa ni idibo yoo waye laarin aago mejila si meji ọsan.

O rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ lati gba alaafia laaye ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo naa. O ni awọn ko ni i ṣe’gbe lẹyin oludije kankan nitori iṣọkan ẹgbẹ lawọn wa fun.

Leave a Reply