Oyetọla bura fawọn adajọ kootu ibilẹ ko-tẹ-mi-lọrun meji l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti sọ pe ijọba oun ko ni i dawọ duro ninu gbogbo igbesẹ lati fi iṣẹ rọ awọn adajọ lọrun, ki wọn le maa ṣedajọ lai ṣegbe si ẹyin ẹnikankan.

Lasiko to n ṣebura fun awọn oadajọ tuntun meji fun kootu ibilẹ ko-tẹ-mi-lọrun (Customary Court of Appeal), niluu Oṣogbo ni gomina sọrọ ọhun. O ni oun nigbagbọ ninu idajọ ododo ti ko ni eru ninu, ti ko si mu ẹru kankan lọwọ rara.

Awọn mejeeji ọhun ni Adajọ Ayọade Aderẹmi Adeṣina ati Adajọ Ojo Ọlayinka Muibat. Bi wọn ṣe bura fun wọn tan ni gomina fi kọkọrọ ọkọ tuntun ti wọn yoo maa lo le wọn lọwọ.

Oyetọla ṣapejuwe ẹka eto idajọ gẹgẹ bii ireti awọn araalu, bẹẹ lo ni ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun yoo jẹ ibi isadi fun ẹnikẹni ti ko ba ri idajọ ododo gba lati kootu agbegbe ibilẹ kọọkan.

Gomina waa ke si awọn adajọ mejeeji naa lati fi otitọ inu ṣiṣẹ, ki wọn ma ṣe ja awọn araalu ni tan-an-mọ, ki wọn si di opo iwa ọmọluabi ti gbogbo eeyan mọ ẹka eto idajọ ipinlẹ Ọṣun mọ.

O ni wọn gbọdọ maa ranti atubọtan ninu gbogbo idajọ ti wọn ba n ṣe, ki wọn si lo aaye tuntun ti wọn bọ si naa fun idagbasoke ọmọniyan ati tipinlẹ Ọṣun.

Bakan naa lo ṣeleri pe gbogbo atilẹyin to yẹ nijọba yoo fun awọn adajọ naa lati le ṣiṣẹ wọn lai foya rara.

Ninu ọrọ idupẹ rẹ, Onidaajọ Ayọade Aderẹmi Adeṣina dupẹ fun anfaani ti gomina fun wọn lati sin ipinlẹ Ọṣun. O ṣeleri pe awọn yoo di opo idajọ ododo mu, bẹẹ ni awọn ko ni i bẹru ẹnikẹni lati huwa ti ko tọ.

Leave a Reply