Oyetọla bura fawọn alaamojuto kansu l’Ọṣun, o ni ijọba ko gbọdọ ka iwa ibajẹ mọ wọn lọwọ

Florence Babaṣọla

Irọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, ṣebura fawọn igbimọ alaamojuto mọkandinlaaadọrin ti wọn yoo maa ṣakoso ijọba ibilẹ atijọba agbegbe titi digba ti idibo yoo fi waye.

Lasiko ibura naa, eleyii to waye ninu gbọngan awọn oṣiṣẹ ijọba ibilẹ ni Abere, Oyetọla rọ awọn eeyan naa lati jẹ olotitọ, ki wọn ri iyansipo wọn gẹgẹ bii ọwọ Ọlọrun, ki wọn si fi ibẹru Ọlọrun kun ohun gbogbo ti wọn yoo maa ṣe.

Gomina sọ fun wọn pe iwa akoyawọ ati ododo nijọba n reti lọwọ wọn, ki wọn si mu iṣẹ wọn ṣe ni kiakia lati le jẹ kawọn araalu ri ere ijọba tiwa-n-tiwa lasiko, eleyii to ni yoo tubọ mu ki ọkan wọn fa si ẹgbẹ oṣelu APC.

O ni ki wọn nawọ ifẹ si awọn ti wọn jọ du ipo naa, ṣugbọn ti ko bọ si lọwọ, ki wọn si sa gbogbo ipa wọn lati ri i pe iṣejọba ẹgbẹ oṣelu APC rẹsẹ walẹ nijọba ibilẹ ti wọn ba wa.

Gomina fi kun ọrọ rẹ pe iṣejọba toun yago fun iwa jẹgudujẹra patapata, bẹẹ ni ko si akọsilẹ ina-apa latọdọ oun, o waa rọ awọn alaamojuto ijọba ibilẹ tuntun ọhun lati kọ ẹkọ lara oun, ki wọn si yago fun ohunkohun to le tapo si aṣọ aala wọn.

Bakan naa ni gomina sọ pe iṣẹ takuntakun ti ọkọọkan awọn eeyan yi ṣe lagbegbe wọn lo ka wọn yẹ fun ipo naa, o si ke si wọn lati tubọ maa pa aṣẹ ẹgbẹ Onitẹsiwaju mọ.

Oyetọla waa parọwa si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ ti orukọ wọn ko jade ninu igbimọ naa lati fọwọ-wọnu, ki wọn si nireti ninu iṣẹ nla ti ẹgbẹ yoo gbe le wọn lọwọ lọjọ iwaju.

Ninu ọrọ Kọmiṣanna fun ọrọ ijọba ibilẹ l’Ọṣun, Adebayọ Adeleke, o dupẹ lọwọ gomina fun bo ṣe yan awọn olorukọ rere lọkunrin ati lobinrin si ipo naa.

Adeleke rọ gbogbo wọn lati tubọ fara jin fun sisin awọn araalu, ki wọn la awọn eeyan wọn lọyẹ lori pataki iforukọsilẹ kaadi awọn oludibo to n lọ lọwọ, ki wọn ma si ṣe ṣe ohunkohun to le ja ijọba kulẹ.

Ninu ọrọ idupẹ aṣoju awọn alaamojuto naa, Ọnarebu Samuel Abiọdun Idowu, o ni awọn mọriri igbagbọ ti gomina ni ninu awọn, o si ṣeleri pe awọn yoo jẹ aṣoju rere fun gomina nijọba ibilẹ onikaluku.

 

Leave a Reply