Oyetọla gbẹsẹ kuro lori ofin konilegbele l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina Adegboyega Oyetọla ti ipinlẹ Oṣun ti sọ pe awọn araalu lanfaani bayii lati wa nita kọja aago mẹjọ alẹ.

Ọsẹ meji sẹyin ni gomina paṣẹ ofin konilegbele tuntun ninu eyi to ti sọ pe ko gbọdọ si ẹnikeni nita laarin aago mẹjọ alẹ si mẹfa idaji latari wahala to ṣẹlẹ lẹyin iwọde SARS.

Ṣugbọn ninu atẹjade kan ti Kọmisanna feto iroyin rẹ fi sita laipẹ yii, o ni ki onikaluku maa ba iṣẹ wọn lọ titi dasiko to ba wu wọn, ki wọn si yago fun ohunkohun to ba le da omi alaafia ipinlẹ Ọṣun ru.

 

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Igbẹjọ Timothy Adegoke: Adedoyin ṣepe fawọn oniroyin ni kootu

Florence Babaṣọla, Oṣogbo Iyalẹnu lo jẹ fawọn oniroyin laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, yii, nigba ti Dokita …

Leave a Reply

//ashoupsu.com/4/4998019
%d bloggers like this: