Oyetọla gbe aba eto-iṣuna ọdun 2021 lọ fawọn aṣofin l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni Gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla, gbe aba eto iṣuna ọdun 2021 lọ siwaju awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin.

Oyetọla sọ pe biliọnu to din diẹ ni aadọfa naira, (#109.9b) nipinlẹ Ọṣun yoo na lọdun to n bọ.

Ninu atupalẹ bọjẹẹti naa, owo-oṣu awọn oṣiṣẹ ati gbogbo nnkan to ni i ṣe pẹlu eto iṣuna ni yoo gba owo to pọ ju nitori nnkan to le ni biliọnu lọna mẹtadinlogoji naira ni wọn fẹẹ na le e lori.

Eto ẹkọ ni yoo tun gba owo to pọ tẹle ti iṣuna, nigba ti ọrọ ilera yoo tẹle e.

Ninu ọrọ Olori ile, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, o gboṣuba fun Oyetọla pẹlu bo ṣe fi ọpọlọ pipe yanju eto iṣuna ọdun 2020 lai fi ti ajakalẹ arun korona ṣe.

O ni kijọba wa ọna lati maa pawo wọle labẹnu dipo bo ṣe jẹ pe owo lati ọdọ ijọba apapọ nikan ni wọn n gbọkan le.

Leave a Reply