Oyetọla kilọ fun wọn l’Ọṣun: Ẹ yaa da gbogbo ohun tẹ ẹ ji pada laarin ọjọ mẹta pere

Gomina Adegboyega Oyetọla ti ipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ pẹlu ikilọ to lagbara pe ki gbogbo ẹni to ba lọwọ ninu jiji awọn ẹru ijọba atawọn ounjẹ iranwọ COVID-19 ko tete yaa da wọn pada laarin wakati mejilelaaadọrin, iyẹn ọjọ mẹta pere, aijẹ bẹẹ, gbogbo wọn pata lo maa fimu kata ofin niwaju adajọ laipẹ.

Ọjọ Aiku, Sannde yii, ni gomina ọhun paṣẹ yii nigba to n ṣabẹwo si awọn ile ikẹrusi tawọn araalu kan jalẹkun wọn, ti wọn si ha awọn ounjẹ tijọba ko pamọ sibẹ.

Oyetọla ni iyalẹnu gbaa lo jẹ foun lati ri bawọn janduku ati araalu ṣe laya lati ko awọn ẹru ọhun lai bẹru ofin, ti wọn si ko gbogbo ẹru to wa ni ile eru naa. O rọ awọn ti wọn lọwọ si kiko ẹru yii, lati tete lọọ da a pada fun alaga ijọba ibilẹ wọn tabi aafin ọba alaye to ba sun mọ wọn ju lọ lati oni titi di oru Ọjọbọ, Wẹsidee, to n bọ yii.

O kilọ pe bii afurasi ọdaran lawọn maa fi pampẹ ofin gbe ẹnikẹni to ba kọ lati da awọn ẹru naa pada, ijọba yoo si ba onitọhun ṣẹjọ.

Lara awọn ibi ti gomina ati ikọ rẹ ṣabẹwo si ni Ọṣun Ankara, ni Irojo, niluu Ileṣa, ati ile ẹru to wa ni Ẹdẹ, nipinlẹ naa.

2 thoughts on “Oyetọla kilọ fun wọn l’Ọṣun: Ẹ yaa da gbogbo ohun tẹ ẹ ji pada laarin ọjọ mẹta pere

  1. You call it,covid19 palliative, did you have another covid19 that is coming in 2021, this means all this yeye apc government no what you to citizens is bad,but remember that there’s god

Leave a Reply