Oyetọla ni ile-ẹkọ awọn olukọni agba niluu Ileṣa yoo di fasiti laipẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti kede mimu agbega ba ile-ẹkọ olukọni agba to wa niluu Ileṣa, o ni ibẹ yoo di fasiti laipẹ.
Nibi eto kan ti wọn ti fa ọsibitu itọju awọn agbalagba, eleyii ti awọn ọmọ bibi ilu Ileṣa kọ, le awọn alakooso Obafemi Awolowo University Teaching Hospital (OAUTHC), lọwọ lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni gomina ti sọrọ naa.
O ni oun ti yẹ ibeere awọn eeyan ilu naa ati ti ọba wọn, HIM Ọba (Dokita) Adekunle Aromọlaran, Ọwa Obokun ti ilẹ Ijeṣa, wo finnifinni, oun si ti fọwọ si i pe ki ile-ẹkọ naa di fasiti kikun.
Lati le jẹ ki iṣẹ naa ya kiakia, Oyetọla ni ijọba ti bẹ ọkan lara awọn ileeṣẹ to dangajia lorileede yii, KPMG, lọwẹ, lati ṣe agbekalẹ igbesẹ tijọba yoo gbe.

Ninu ọrọ rẹ, Aṣiwaju ilẹ Ijeṣa, Oloye Yinka Faṣuyi, dupẹ pupọ lọwọ Gomina Oyetọla fun oore nla to ṣe fun wọn, o ni manigbagbe ni.
O ṣalaye pe ọjọ ti pẹ ti awọn ti n lọgun pe ki ile-ẹkọ naa, eleyii ti wọn da silẹ lọdun mẹrinlelogoji sẹyin, di fasiti, ṣugbọn ti Oyetọla ṣe e fun awọn wẹrẹ yii.
O ni ki gomina fọkan balẹ, nitori idibo oṣu Keje, lawọn yoo fi san oore pada fun un. O fi kun ọrọ rẹ pe niwọn igba ti gomina ti fi igbesẹ naa pọn awọn le, gbogbo ilẹ Ijeṣa yoo fi ibo wọn pọn oun naa le.

Leave a Reply