Oyetọla sọ konilegbele Ọṣun di aago mẹjọ alẹ si mẹfa aarọ

Jide Alabi

Lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni ayipada ti de ba ofin konilegbele to wa nipinlẹ Ọṣun. Lati aago mẹjọ alẹ si aago mẹfa aarọ ni isede yoo fi maa wa bayii, dipo wakati mẹrinlelogun tijọba pasẹ tẹlẹ.

Gomina ipinle Ọṣun, Adegboyega Oyetọla, lo sọrọ naa ni Ọjọbọ, Wesidee, ọsẹ yii, ninu atejade kan to fi sita nipasẹ Akọwe ijọba, Ọmọọba Wọle Oyebamji. O ni pẹlu bi awọn araalu ṣe tẹle ofin konilegbele tijọba kede lati mu ki gbogbo nnkan rọlẹ, ki alaafia si wa niluu, oun ti ṣe atunṣe si ofin ọhun bayii.

Gomina fi kun un pe awọn agbofinro yoo ṣi wa kaakiri igboro lati mu ki nnkan lọ bo ṣe yẹ laarin ilu. O fi kun un pe lati aago mẹfa aarọ si aago mẹjọ alẹ ni awọn ọlọkada yoo fi maa ṣiṣẹ wọn. Bi yoo si ṣe wa niyi bi ijọba ba fopin si konilegbele patapata paapaa.

Oyetọla dupe lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun fun ifọwọsowọpọ wọn laarin ọjo marun-un ti  konilegbele naa fi wa. Bẹẹ lo gboṣuba fun awọn ọdọ fun bi wọn ṣe fi iwa ọmọluabi han, ti wọn si fopin si iwọde ti wọn n ṣe. O si ṣeleri atilẹyin fun wọn.

Leave a Reply