Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Akolo ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku nilẹ yii, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ni awọn afurasi oyinbo Chinese mẹtala kan wa bayii. Ẹsun ti wọn fi kan wọn ni pe wọn wa kusa lọna aitọ niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
ALAROYE gbọ pe l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Keje yii, lọwọ tẹ awọn afurasi naa lagbegbe GRA. Awọn oyinbo Ṣinko ọhun jẹwọ pe ni gbogbo ijọba ibilẹ mẹrẹẹrindinlogun to wa nipinlẹ naa ni awọn ti ni awọn ilẹ ti awọn ti n wa kusa lọna aitọ, nitori awọn ko gba aṣẹ lọwọ ijọba.
Bakan naa ni wọn sọ pe oṣiṣẹ ileeṣẹ oyinbo Chinese kan ti wọn n pe ni W. Mining Global Service Limited, to wa ni agbegbe Ọlayinka, nijọba ibilẹ Ifẹlodun, nipinlẹ Kwara, ni awọn n ba ṣiṣẹ.
Iwadii fi han pe gbogbo awọn oyinbo Chinese mẹtẹẹtala yii, ọkunrin mejila, obinrin kan, ni wọn n ṣiṣẹ ni ileeṣẹ ti wọn darukọ yii lai gba iwe aṣẹ iṣẹ ṣiṣe, iwe ‘mo ṣabẹwo wa si Naijiria’ ni wọn gba lati orile-ede China, ti wọn si kuro niluu Abuja ti wọn de si, ti wọn wa si ipinlẹ Kwara.
Ajọ naa ni awọn yoo foju awọn oyinbo yii bale-ẹjọ lẹyin ti awọn ba pari gbogbo iwadii.
Aworan awọn oyinbo Chinese to ha sakolo EFCC ni Kwara ree