Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ṣe ẹ ranti Pasitọ Ebenezer Ogunmẹfun Ajigbọtoluwa ta a mu iroyin ẹ waa fun yin lọsẹ to kọja pe awọn ọlopaa sọ pe o fun tẹgbọn-taburo loyun l’Abẹokuta, ati pe o tun ṣẹyun ọhun fun wọn, baba naa ti ṣalaye ara ẹ f’ALAROYE. O loun ko fun tẹgbọn-taburo loyun, ọkan ninu wọn loun n ba sun to doyun, to si fi oyin ọhun bimọ foun.
Kọmandi ọlọpaa to wa ni Eleweeran l’Abẹokuta ni wọn ti ṣafihan Ajigbọtoluwa lọjọ Aje, Mọnde, nibẹ lo ti sọ pe ìyà ti awọn ọlọpaa fi jẹ oun lo jẹ ki oun jẹwọ ohun ti oun ko ṣe, pe oun fun awọn ọmọ iya kan naa tọjọ ori wọn jẹ mẹrindinlogun ati mẹtala loyun.
Pasitọ ti ṣọọṣi ẹ n jẹ ‘Church of The Lord of Isreal’ to wa ni Olomoore l’Abẹokuta naa sọ pe eyi to jẹ ẹgbọn ninu awọn ọmọ naa loun ati ẹ jọ fẹra awọn pẹlu aṣẹ awọn obi wọn, to fi di pe o loyun foun, to si bimọ obinrin kan.
Ajigbọtoluwa sọ pe,’’Ẹmi okunkun lo n da ọmọ ti mo fẹ yẹn laamu, awọn obi ẹ dẹ sọ fun mi pe ti mo ba ṣe itusilẹ fun un to si gbadun, ki n fẹ ẹ. Mo ṣiṣẹ naa fun un o si gbadun, nigba yẹn la bẹrẹ si i fẹra wa, to fi di pe o loyun fun mi. Obinrin lọmọ to bi fun mi, Christiana Boluwatifẹ la sọ ọ, awọn obi ẹ fọwọ si fifẹ ti mo fẹ ẹ, a jọ ṣekomọ ni, ọmọ to bi fun mi ti le lọdun kan bayii.
‘’ Ọmọ ọdun mọkandinlogun ni awọn obi iyawo mi pe ọjọ ori ẹ fun mi, mi o mọ pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni’’
Lori ti aburo ti wọn lo tun fun loyun, pasitọ yii sọ pe irọ ni, oun ko mọ nnkan kan nipa oyun aburo, oun ko ba a sun ri.
Jibiti miliọnu kan aabọ ti wọn lo tun lu awọn obi awọn ọmọ yii nkọ, iyẹn nigba to fi dandan le e pe ki wọn maa waa gbe layika ṣọọṣi. Pasitọ Ogunmẹfun to ni 1986 loun ti n ṣiṣẹ pasitọ, sọ pe oun gbowo lọwọ wọn loootọ, ṣugbọn ki i ṣe miliọnu kan aabọ, ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira(120,000) pere ni.
Awọn ikoko asejẹ ti wọn tun ba lọwọ ẹ yii nkọ, (nitori awọn ọlọpaa ṣafihan ẹ pẹlu ikoko meji ti wọn ni oogun ibilẹ ninu ni). Pasitọ Ogunmẹfun dahun pe oun fi n ṣoogun jẹdijẹdi ni. O ni Ọlọrun ko kọ ewe ategbo lilo, o wa ninu Bibeli bẹẹ, gẹgẹ bo ṣe wa nibẹ pe eeyan le fẹyawo meji naa ni.
Ajigbọtoluwa sọ pe Ẹmi Eṣu lo ya oun lo toun fi huwa to lodi sofin Ọlọrun ati teeyan, iyẹn nipa owo ti oun gba lọwọ obi awọn ọmọ yii, o ni eeyan Ọlọrun ni Ẹmi Eṣu maa n wa kiri.
Pasitọ Ogunmẹfun ni kawọn eeyan foriji oun, kijọba atawọn obi awọn ọmọ yii naa foriji oun, Eṣu lo jẹbi.
Boya Eṣu ni tabi Ẹmi Eṣu, CP Edward Ajogun ti ni ki pasitọ yii ṣi wa ni gbaga, ki wọn ma si jẹ ko pẹ ki wọn too gbe e lọ sile-ẹjọ