Paali siga, Indomie lawọn ajinigbe to ji ọkunrin agbẹ kan gbe l’Ekiti n beere

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Awada lawọn eeyan kọkọ pe ọrọ naa, nigba ti awọn ajinigbe to ji ọkunrin agbẹ kan, Ọgbẹni Adewumi Babatunde, ẹni ọdun mẹtalelaaadọta gbe, ni Omu-Ekiti, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, pe awọn mọlẹbi ọkunrin naa lẹyin ọjọ kẹta ti wọn ti ji i gbe, ti wọn si n beere fun paali siga, Indomie ati miliọnu meji Naira.

Ẹnikan to sun mọ mọlẹbi naa to ba ALAROYE sọrọ sọ pe ni kutukutu aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tuside, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹta, ni awọn ajinigbe naa pe iyawo agbẹ yii, ti wọn sì sọ gbogbo nnkan ti wọn fẹẹ gba lọwọ awọn mọlẹbi naa ki wọn too le tu ọkunrin naa silẹ.

Babatunde yii ni awọn agbebọn kan ti wọn dihamọra nnkan ija oloro loriṣiiriṣii da duro nigba to n lọ si oko rẹ lati Omu-Ekiti si ilu Ayede, nijọba ibilẹ Ọyẹ, nipinlẹ Ekiti, ti wọn si ji i gbe wọnu igbo lọ.

Iyawo ọkunrin agbẹ yii, Arabinrin Bọsẹde Babatunde, sọ pe

ọkọ oun gbe ọkada rẹ nirọlẹ ọjọ Aiku,  lati lọọ wo oko rẹ to wa lọna Omu-Ekiti si ilu Ayede, nibẹ ni awọn agbebọn ti wọn ko din ni marun-un, ti da a duro, ti wọn si kọju rẹ sinu igbo kan ti ẹnikan ko mọ.

Obìnrin naa to n sọrọ pẹlu ibanujẹ ni ni kutukutu idaji aarọ ọjọ Iṣẹgun ni awọn ajinigbe ọhun pe sori aago oun lati beere fun paali siga, Indomie ati miliọnu meji gẹgẹ bii owo itusilẹ fun ọkọ oun.

O ṣalaye pe lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ ni wọn ṣẹṣẹ too gba lati din owo itusilẹ ti wọn n beere fun ku si miliọnu meji.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Ọba ilu ọhun, Adeyẹye Ogundeyi, sọ pe ìṣẹlẹ ijinigbe awọn ọmọ ilu naa, ni pataki ju lọ, laarin  awọn agbẹ ti n di lemọ-lemọ.

O parọwa sijọba ipinlẹ Ekiti pe ki wọn pese eto aabo to peye fun awọn eeyan agbegbe naa, ni pataki ju lọ, awọn agbẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, Alukoro ọlọpa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe oun ko ti i gbọ nipa ìṣẹlẹ naa, ṣugbọn oun yoo beere lọwọ ọga ọlọpaa to wa ni agbegbe ọhun.

Ọga Amọtẹkun ipinlẹ Ekiti, Ajagun-fẹyinti Joe Kọmalafẹ, sọ pe awọn ọmọ ogun oun ti wa ni gbogbo inu igbo to wa ni agbegbe naa lati ri i pe wọn gba ọkunrin agbẹ naa silẹ.

Leave a Reply