Gbenga Amos, Abẹokuta Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti kede pe ti gbajugbaja olorin Zaa Zuh nni, Habeeb Okikiọla, tawọn eeyan mọ si Portable, ba mọ iwọn ara ẹ, ko yaa fẹsẹ ara ẹ rin wa solu-ileeṣẹ wọn to wa l’Eleweẹran, l’Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, lati waa dahun ẹsun iwa ọdaran kan …
Read More »Ọwọ tẹ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n da wọn laamu ni Sagamu
Gbenga Amos, Abẹokuta Mẹfa ninu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n da awọn eeyan ilu Sagamu ati agbegbe rẹ laamu tawọn ọlọpaa ti n wa nipinlẹ Ogun ti ko sọwọ wọn bayii, wọn si ti fọwọ ofin mu wọn. Lara awọn ti ọwọ tẹ gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ …
Read More »Awọn ọmọọta kọ lu ọkọ awọn akọroyin to kọwọọrin pẹlu Tinubu
Jọkẹ Amọri Laarin Ebute Ero si Adeniji, si Iga Iduganran, nibi ti aafin ọba Eko wa ni awọn ọmọọta kan ti kọ lu mọto awọn akọroyin to kọwọọrin pẹlu gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan gẹgẹ bii oludije funpo aarẹ ninu ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, lọjọ …
Read More »Oyebamiji lo wọle ibo Ekiti, ṣugbọn Ṣẹgun Oni loun ko ni i gba
Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Lẹyin ti ajọ eleto idibo ti kede oludije lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC, Biọdun Oyebamiji gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo to waye ni Satide, ọjọ Abamẹta. ọsẹ to kọja yii, ẹni to ṣe ipo keji ninu eto idibo naa lati inu ẹgbẹ SPD, Ṣẹgun …
Read More »Oludije APC, Oyebamiji, jawe olubori ni wọọdu rẹ
Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ninu ibo ọọdunrun ti wọn di ni wọọdu oludije funpo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Biọdun Oyebamiji, mẹrin pere lo ṣẹku fun awọn alatako, mẹrindinlọọọdunrun loun nikan ko. Wọọdu kẹfa, Yuniiti kẹta, Okelele, to wa Ikogosi-Ekiti, ni Oyebamiji ti dibo rẹ, to si ni ibo ọọdunrun din …
Read More »Oludije APC, Oyebamiji, jawe olubori ni wọọdu rẹ
Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ninu ibo ọọdunrun ti wọn di ni wọọdu oludije funpo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, Biọdun Oyebamiji, mẹrin pere lo ṣẹku fun awọn alatako, mẹrindinlọọọdunrun loun nikan ko. Wọọdu kẹfa, Yuniiti kẹta, Okelele, to wa Ikogosi-Ekiti, ni Oyebamiji ti dibo rẹ, to si ni ibo ọọdunrun din …
Read More »Ibo gomina l’Ekiti: Ṣẹgun Oni jawe olubori ni wọọdu rẹ
Taofeek Surdiq Ibo okoolerugba o din meji (218), ninu ibo ojilenigba o le meji (242), ni gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Oloye Ṣẹgun Oni, fi gbẹyẹ lọwọ awọn oludije ẹgbẹ rẹ ni wọọdu idibo rẹ to wa ni Wọọdu kẹrin, Yuniiti kẹfa, ni agbegbe Ọgbọn Iro, Ifaki, nijọba ibilẹ Ọyẹ Ekiti. …
Read More »Olubadan fi gomina Kano joye Aarẹ Fiwajoye ilẹ Ibadan
Ọlawale Ajao, Ibadan Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba (Ọmọwe) Mohood Lekan Balogun, ti fi Gomina ipinlẹ Kano, Ọmọwe Abdullahi Umar Ganduje, joye Aarẹ Fiwajoye ilẹ Ibadan, bẹẹ lo fi iyawo ẹ, Ọjọgbọn Hafsat Ganduje, jẹ Yeye Aarẹ Fiwajoye ilu naa. Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii, leto …
Read More »Wọn yan Adebayọ Shittu gẹgẹ bii adari iponlogo ibo aarẹ fun Tinubu
Ọlawale Ajao, Ibadan Wọn ti yan minisita feto iroyin nilẹ yii tẹlẹ, Alhaji Adebayọ Shittu, gẹgẹ bii alakooso eto ipolongo ibo aarẹ fun Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti i ṣe oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu All Progresives Congress (APC). Igbimọ ti yoo maa polongo ibo fun Tinubu ọhun ni …
Read More »Ọwọ EFCC tẹ awọn to fẹẹ fowo ra ibo ‘Ekiti
Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti ṣafihan aọn kan tọwọ tẹ pe wọn fẹẹ fun aọn eeyan lowo lati ra ibo wọn. Owo tuulu tuulu ni wọn ba lọwọ awọn eeyan naa ni ibudo idibo gẹgẹ bi ileeṣẹ tẹlifiṣan Channel ṣe sọ. Oju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa mu wọn, ti …
Read More »Ọlawale Ajao, Ibadan Tẹslim kilọ fun Makinde: To o ba gbidanwo lati yọ igbakeji rẹ, wahala nla ni fun ọ Ikilọ ti lọ sọdọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, pe to ba dan gbogbo igbiyanju ẹ lati yọ Igbakeji rẹ, Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan, to ti darapọ mọ ẹgbẹ APC bayii nipo, yoo yọ silẹ fun un. Oludije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ninu ibo gomina to n bọ nipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Teslim Fọlarin lo ṣe ikilọ yii lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, latẹnu Oludamọran rẹ lori eto iroyin, YSO Adeniyi. Fọlarin ni gbogbo igbesẹ awọn aṣofin ti Ṣeyi Makinde ti pin owo fun ti wọn fẹẹ yọ Ọlaniyan ko ni i ṣee ṣe rara nitori ida meji ninu mẹta awọn ọmọ igbimọ ni wọn gbọdọ fọwọ si iyọnipo naa. O ni lara awọn aṣofin naa ti wọn ṣi ni ẹri ọkan, atawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ ti wọn dibo yan ọkunrin naa lati lo ọdun mẹrin nipo gẹgẹ bii igbakeji gomina ni yoo lodi si igbesẹ gomina yii. O ni iyansipo gomina yii ṣi wa labẹ ofin, ti ko si si ohunkohun to le ṣi i nidii titi di ọjọ klọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun to n bọ. Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to pari yii, ni awọn ọmọ ileegbimọ aṣọfin ipinlẹ Ọyọ bẹrẹ igbesẹ lati yọ Igbakeji gomina wọn naa, Ẹnjinnia Rafiu Ọlaniyan nipo. Lara ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o hu awọn iwa ti ko tọ, o ṣe awọn owo kan to wa ni ikapa rẹ mọkumọku, aṣilo ipo to wa gẹgẹ bii igbakeji gomina, bẹẹ ni wọn tun sọ pe o fi ọfiisi ati iṣẹ to yẹ ko maa ṣe gẹgẹ bii igbakeji gomina silẹ, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Awọn aṣofin mẹrinlelogun ni wọn ti fọwọ si iyọnipo rẹ latari awọn ẹsun ti wọn fi kan an yii.
Ọlawale Ajao, Ibadan Tẹslim kilọ fun Makinde: To o ba gbidanwo lati yọ igbakeji rẹ, wahala nla ni fun ọ Ikilọ ti lọ sọdọ Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, pe to ba dan gbogbo igbiyanju ẹ lati yọ Igbakeji rẹ, Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan, to ti darapọ mọ ẹgbẹ APC …
Read More »