Papa iṣere Ilọrin la ti maa ṣe ayẹyẹ ‘Durbar’ ọdun yii – Ilọrin Emirate 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Awọn igbimọ to n mojuto bi ayẹyẹ Durbar to maa n waye niluu Ilọrin lọjọ keji, ọdun lleya, ni gbagede ọba Ilọrin, ti sọ pe papa iṣere tipinlẹ Kwara, to wa nìyi naa ni tọdun yii yoo ti waye.

Alaga igbimọ ayẹyẹ ọhun, Onimọ ẹrọ, Suleman Yahaya Alapansanpa, lo fi ọrọ naa lede fun awọn oniroyin nirọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọṣẹ to kọja, o ni ara ọtọ ni awọn fẹ ki tọdun yii jẹ, ati pe awọn fẹ ko gba ẹgbẹlẹgbẹ ero, eyi lo fa a tawọn yoo fi lo gbagede ọba lọdun yii.

Alapansanpa tẹsiwaju pe ọjọ keji ọdun lleya ti i ṣe ọjọ kọkanlelogun, oṣu keje, ọdun yii, ni ayẹyẹ naa yoo waye. O ni gbogbo ọmọ Emirate pata nile, loko, lẹyin odi lawọn pe ti aabo ẹmi ati dukia si wa fun gbogbo ẹni to ba peku sibẹ

 

Leave a Reply

//betzapdoson.com/4/4998019
%d bloggers like this: