Pasitọ ṣe gbaju-ẹ fawọn to waa ṣe isọji fun, owo ati ọpọlọpọ foonu wọn lo ko lọ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gẹgẹ bii ọrọ inu Bibeli to sọ pe nigba ti aye ba n lọ sopin, oriṣiirṣii iṣẹlẹ kayeefi ni yoo maa ṣẹlẹ. Iru iṣẹlẹ irọlẹ aye bẹẹ lo waye n’Ibadan lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, nigba ti odidi pasitọ ko owo, ẹrọ ibanisọrọ ati nnkan ẹṣọ ara awọn ọmọ ijọ rẹ lọ lasiko ti wọn diju, ti wọn n gbadura lọwọ.

ALAROYE gbọ pe Oluṣọ-Agutan naa, Pasitọ (Dokita) Owen Abraham, to jẹ ọmọ orile-ede Gambia, funra rẹ lo ṣagbekalẹ isọji ọlọjọ marun-un ọhun laduugbo Agbowo, n’Ibadan.

Ohun to si mu ki ero pọ daadaa laarin ọjọ maraarun ni bi Pasitọ Abraham ṣe kọ ọ sibi iwe ikede isọji naa pe oun yoo ṣeranlọwọ owo nla nla fawọn alaini, bẹẹ lawọn ọdọ yoo janfaani ẹbun ẹkọ-ọfẹ.

Lọjọ kọkanlelọgbọn (31), oṣu Kẹta, ọdun 2023, leto ọhun bẹrẹ, to si pari lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹrin, ọdun yii kan naa.

Lọjọ ti isọji ọhun maa pari gan-an ni oluṣọ-agutan yii paṣẹ fawọn agutan rẹ pe ki gbogbo wọn ko ohun gbogbo to ba wa lọwọ wọn silẹ, ẹmi Ọlọrun sọ foun pe ko gbọdọ si foonu, owo, tabi ohunkohun to jẹ ti aye kankan lọwọ ẹnikẹni titi ti aṣekagba isọji naa yoo fi pari.

Gẹgẹ bii ilana awọn Onigbagbọ, nigba ti eto adura naa n lọ lọwọ, gbogbo wọn diju, ṣugbọn ki ni wọn gbadura tan si ni, oju ti awọn ọmọ ijọ yoo ya bayii, ati pasitọ, ati gbogbo nnkan ti wọn ko si dokita naa lọwọ ti poora.

Ọkan ninu awọn to padanu dukia wọn sọwọ wolii eke to pera ẹ lojiiṣẹ Ọlọrun yii, Abilekọ Grace Akintọla, fidi ẹ mulẹ pe awọn opó lo pọ ju nibi eto naa, nitori ileri iranlọwọ owo nla nla ti jagunlabi ṣe fawọn alaini.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Obinrin Ibo kan ta a jọ n gbe adugbo kan naa lo pe mi sibi isọji yẹn, o ni pasitọ yẹn ti ṣeleri pe oun maa fun awọn eeyan lowo nla nla, owo ti awọn oloṣelu gan-an ko le fun eeyan. Bẹẹ lo tun ni oun maa fun ẹnikan ninu awa ta a ba wa sibẹ ni odidi ile kan ti gbogbo nnkan ti pe sinu ẹ.

“Pasitọ yii ta ike omi kan fun wa ni ẹgbẹrun marun-un o din igba Naira (₦4,800), ọpọ eeyan lo sí ra omi yẹn.

” Pasitọ Abrahamu fi wa silẹ sinu aawẹ ati adua, nigba to di ọjọ aṣekagba eto, ṣadeede la wa a ti, ti a ko ri i mọ. Gbogbo igbiyanju wa lati ri i ba sọrọ ko so eeso rere, nitori gbogbo ba a ṣe n gbiyanju lati pe e sori foonu rẹ to, aago rẹ ko lọ rara”.

Leave a Reply