Pasitọ Abraham ni aye ti fẹẹ parẹ, o ni kawọn ọmọ ijọ dawo foun ki wọn le rọrun wọ l’Omuo-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti tẹ Pasitọ ijọ Christ High Commission Ministry, ti gbogbo eeyan tun mọ si Royal Christ Assembly, to wa ni Kaduna, Nuah Abraham.
Ẹsun ti wọn fi kan pasitọ yii ni pe o ko awọn ọmọ ijọ rẹ wa lati ipinlẹ Kaduna si ori oke kan ni Omuo-Ekiti, o si gba ẹgbẹrun lọna igba Naira lọwọ wọn pe oun n gbadura fun wọn lori oke naa ki wọn le ri ọrun wọ, o ni aye yoo parẹ laarin ọjọ mẹsan-an ti wọn ba fi wa lori oke ọhun.
Nibi ti pasitọ to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Ekiti naa ti n ṣeto adura naa lọwọ lawọn ọmọ ijọ rẹ kan ti fọrọ naa to awọn araalu leti, ti wọn si pada lọọ fi to awọn agbofinro leti.
Awọn agbofinro ko jafara rara ti wọn fi lọọ mu pasitọ to n ṣe gbaju-ẹ fun awọn ọmọ ijọ rẹ yii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe ọkan lara mọlẹbi awọn ọmọ ijọ naa lo fi ọrọ yii to awọn ọlọpaa leti pe pasitọ yii lo sọ fun gbogbo ọmọ ijọ rẹ pe aye yoo parẹ laarin ọjọ mẹsan-an si akoko naa.
Bakan naa ni wọn lo tun sọ fun ọkan lara awọn ọmọ ijọ naa pe ti aburo rẹ to wa niluu oyinbo ko ba san lara owo adura ti awọn ọmọ ijọ naa san, yoo ku iku ojiji ki ọjọ mẹsan-an too pe.
Abutu ni awọn ti mu pasitọ naa si akata awọn lati ṣalaye bi Ọlọrun ṣe fi han an pe aye yoo parẹ ati bo ṣe gba owo lọwọ awọn ọmọ ijọ pe oun yoo fi ṣe eto adura fun wọn ki wọn le ri ọrun rere wọ ni kete ti aye ba parẹ.
Alukoro ọlọpaa yii sọ pe ọkunrin naa ṣẹṣẹ pada wa si ipinlẹ Ekiti lati Kaduna to ti n gbe lati ọdun meji sẹyin ni.

Leave a Reply