Pasitọ Adeboye naa loun o fẹ SARS mọ o

Kazeem Aderounmu

Olori ijọ Ridiimu kaakiri agbaye, Pasitọ E.O Adeboye, naa ti darapọ mọ ọgọọrọ awọn ọmọ Naijiria lati ke si ijọba orilẹ-ede yii ko fagile ẹṣọ agbofinro SARS, ipakupa ti awọn ọlọpaa n paayan ati idasilẹ ẹṣọ mi-in ti ijọba pe ni SWAT.

Adeboye sọrọ yii lọjọ Wẹsidee, Ọjọru lori ẹrọ abayẹfo (twitter) ẹ, ohun to si sọ ni pe, awọn ọmọ wa lobinrin ko ni le sọ asọtẹlẹ mọ, bẹẹ lawọn ọdọ wa lọkunrin paapaa ko ni le lalaa rere ti a ko ba jẹ ki wọn ri aye gbe. Adeboye sọrọ yii pẹlu aworan kan lọwọ ni, ti wọn si kọ ọ sibẹ wi pe, gbogbo ẹmi pata lo ṣe pataki si Ọlọrun.

Ojiṣẹ Ọlọrun yii ti sọ pe oun fọwọ si iwọde wọọrọ tawọn ọdọ n ṣe tako ẹṣọ SARS, iṣekuṣe ti ọlọpaa n ṣe araalu, ati idasilẹ ẹṣọ agbofinro mi-in ti ijọba pe ni SWAT.

Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni ojiṣẹ Ọlọrun yii ba ijọba apapọ sọrọ lori atunto iṣejọba orilẹ-ede Naijiria, ṣugbọn ti ọrọ ọhun gbodi lara ileeṣẹ Aarẹ.

 

Leave a Reply