Pasitọ Chibuzor fun awọn obi Deborah ni ile fulaati mẹrinla atawọn ẹbun mi-in

Monisọla Saka

O da bii pe iku Deborah, ọmọbinrin ti awọn awọn kan juko pa, ti wọn tun dana sun oku rẹ ni Ṣokoto ko ja si asan bayii pẹlu bi Pasitọ ijọ kan ti wọn n pe ni Omega Power Ministry, Chibuzor Chinyere, ti dide iranlọwọ si awọn ẹbi rẹ, to fun wọn ni ile, mọto atawọn ẹbun oriṣiiriṣii mi-in.
Ojiṣẹ Ọlọrun ti ṣoọṣi rẹ wa nipinlẹ Rivers, Apostle Chibuzor Chinyere, ti pada ribi ba awọn obi Deborah sọrọ lẹyin to kọ ọ sori ikanni Fesibuuku (Facebook) ẹ pe inu oun yoo dun ti oun ba le rẹni ba oun wa nọmba foonu awọn obi ọmọ ti wọn dẹmii ẹ legbodo ọhun, iyẹn Deborah to jẹ akẹkọọ-binrin nileewe giga Shehu Shagari College of Education, to wa nipinlẹ Sokoto.
Lasiko to pe wọn lori aago to le fun eeyan lanfaani ati maa woju ara ẹni ti wọn n pe ni ‘video call’, ni awọn obi Deborah ti gba lati maa ko lọ siluu Port Harcourt gẹgẹ bi alagba naa ṣe da a labaa, ki wọn le bẹrẹ igbe aye ọtun.
Ile fulaati mẹrinla ni ọkunrin naa gbe iwe to ti paarọ orukọ rẹ si tiwọn yii le wọn lọwọ, o ni o ti di tiwọn latoni lọ. O ni ki wọn mu fulaati kan ki wọn maa lo o ninu rẹ, ki wọn si maa gbowo rẹnti iyooku.
Bakan naa ni wọn ra oriṣiiriṣii ohun eelo ile bii aga, awọn ohun eelo idana, bẹẹdi ati gbogbo ohun to le mu ki aye dẹrun sinu ile naa fun awọn eeyan yii.
Lẹyin eyi ni wọn ṣẹṣẹ waa fun wọn ni ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn yoo maa fi ṣe ẹsẹ rin.
Gẹgẹ bi erongba ojiṣẹ Ọlọrun naa, o fun ọmọkunrin ti wọn bi le Deborah ni eto ẹkọ-ọfẹ loke okun.
Ko tan sibẹ, o tun ṣeleri lati ran gbogbo awọn aburo Deborah to ku niwee titi de ipele yunifasiti.
Awọn eeyan naa ko le pa idunnu wọn mọra, niṣe ni iya ati baba Deborah so mọ iranṣẹ Ọlọrun naa, ti wọn si n sunkun ninu fidio kan ti wọn ju sori ẹrọ ayelujara, lasiko ti ongbufọ n tumọ awọn ohun ti pasitọ naa fẹẹ ṣe fun wọn.
O waa rọ awọn eeyan pe ki wọn ni ifẹ ara wọn. O ni Naijiria iba jẹ ibi to daa ju lagbaaye, bi a ba nifẹẹ ara wa, ti a n si n ni ipamọra wa funra wa.
O ni Ọlọrun to da Musulumi naa lo da Onigbagbọ.
Iranṣẹ Ọlọrun naa ni idamẹwaa ati ọrẹ awọn ọmọ ijọ lawọn fi ṣe iranlọwọ fun awọn obi Deborah.
Awọn mọlẹbi tọkọ-tiyawo naa dupẹ pupọ lọwọ Pasitọ Chibuzor fun oore nla ti Ọlọrun gba ọwọ rẹ ṣe fun wọn.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//lephaush.net/4/4998019
%d bloggers like this: