Wolii Ọdunayọ foogun orun sinu ọti fọmọ ọdun mẹrinla, lo ba ba a lo pọ karakara n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Inu àhámọ́ ọgbà ẹwọn Agodi, n’Ibadan, ni oludari ṣọọṣi ìgbàlódé kan, Jimi Ọdunayọ, wa bayii lẹyin ti ọwọ awọn agbofinro tẹ ẹ fun bo ṣe fipa ba ọmọ aladuugbo rẹ laṣepọ.

Ọdunayọ, to jẹ wolii ìjọ Kérúbù ati Serafu kan ti wọn tun n pe ni Oke-Aṣeyọri, ni Opopona Adewale, n’Iyana Church, n’Ibadan, ni wọn lo ti maa n ba ọmọọdun mẹrinla naa, Tọmiwa, ẹni ta a fi ojúlówó orukọ ẹ̀ bo laṣiiri laṣepọ tipẹ.

Wọn ní owo keekeeke ati nnkan ipanu lo fi máa n fa ọmọdebinrin naa loju mọra.

Lọjọ Àbámẹ́ta, Sátidé ọgbọnjọ, oṣù kin-in-ni, ọdun 2021 yii, ni baba agba yii ṣe eyi to bu ú lọwọ nigba to tan ọmọbinrin aladuugbo rẹ yii wọnú yara nile ẹ̀ tó wà l’Opopona Balogun, laduugbo Aṣí, ni Bódìjà, n’Ibadan, to sì fi oògùn oorun sinu ọtí ẹlẹri-dodo fun un mu titi to fi fi ibalopọ hàn ọmọ ọlọmọ leemọ nigba to sun lọ fọnfọn tán.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, nigba ti Tọmiwa tají lẹyin wakati diẹ to ti sun lo ri i pe ihoho ọmọluabi loun wa lori ibusun ni yara baba agba naa.

O bẹrẹ sí í wò tìyanu tìyanu pe nibo loun wa yii. Bó ṣe ni ki oun dide nilẹ lo woye pe ara oun ko mókun tó. Nigba naa lo yẹ ara ẹ̀ wò, to ri í pé gbogbo oju ara oun lo kun fún ẹjẹ. Káàsà! Wolii ti fi kinni nla ba a labẹ jẹ.

Bó ṣe dé inu ile wọn lo ṣalaye ohun tó ṣẹlẹ sí í fún bàbá ẹ̀, ti ìyẹn sí fi ẹjọ baba agbaaya naa sun awọn agbofinro ni teṣan ọlọpaa to wa ninu ọja Bodija, n’Ibadan.

Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Ngozi Ọnadẹkọ fìdí ẹ mulẹ pe lati ọdun 2019 lafurasi ọdaran yii ti n ko ibasun fún Tọmiwa bo ṣe wù u nítorí inú ọgbà kan naa nilé to n gbe pẹlu awọn ọmọdebinrin naa.

“Esi ayẹwo ta a ṣe nileewosan fìdí ẹ mulẹ pe oju ọgbẹ́ to wà lójú ara ọmọbìnrin yẹn ki i ṣe kekere ati pe ibalopọ ni pasitọ fi ṣe ọmọ alabaagbe ẹ̀ leṣe bẹẹ.

Bàbá àgbà tí wọn fẹsun ọdaran kan yii jẹwọ pe loootọ loun bá ọmọọdun mẹrinla naa laṣepọ, ati pe sátánì lo kò sí oun lọkan ti oun ṣe huwa to lodi sofin Ọlọrun ati ofin ilẹ yii naa.

ALAROYE gbọ pe wọn ti gbe pasitọ naa lọ si kootu, ile-ẹjọ sì ti pàṣẹ pé kí wọn fi í pamọ́ sí àhámọ́ ọgbà ẹwọn l’Agodi, n’Ibadan titi ti wọn yóò fi parí igbẹjọ naa.

Leave a Reply