Pasito Kumuyi, olori ijọ Deeper Life, kọ Bibeli tuntun

Olori ati Oludasilẹ ijọ awọn Dipa (Deeper Life) Pasitọ William Kumuyi, ti kọ Bibeli tuntun ni ede Yoruba. Idi eyi ni lati mu imọ Bibeli kun, ati lati ṣe atunṣe si awọn ọrọ ti itumọ wọn ti yipada ni ede Yoruba. Eyi lo ṣe jẹ Pasitọ naa pẹllu awọn onimọ ede Yoruba ni won jọ ṣiṣẹ lori ẹ.

Bii ọdun mẹẹdogun lo gba Kumuyi lati kọ Bibeli ti wọn pe orukọ rẹ ni Bibeli Mimọ Atọka yii, awọn Bible Society of Nigeria ni wọn si tẹ ẹ jade.

Gẹgẹ bii ikede lati ṣọọṣi Dipa, Bibeli yii jẹ eyi to ṣee gbarale pupọ fun itumọ tootọ ninu awọn ohun to wa ninu Bibeli ti ko yeni lati ọjọ yii wa. “Awọn oniwaasu ati olukọni pẹlu awọn ti wọn ba n wa ojulowo itumọ Bibeli lede Yoruba ni iwe ọrọ Ọlọrun tuntun naa yoo wulo fun ju lọ.” Kumuyi funrarẹ lo sọ bẹẹ.

Leave a Reply