Pasitọ luyawo ẹ pa, wọn loogun awọro lo fẹẹ fi i ṣe

Njẹ ẹyin gbọ nipa olori ijọ Omega World Global Ministries? Pasitọ Ukachukwu Enoch Christopher, ti ṣọọṣi rẹ wa nipinlẹ Akwa-Ibom, ẹni to lu iyawo ẹ pa lọsẹ to kọja.

Ohun meji naa la gbọ pe o fa a ti ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlaaadọta (49) yii fi lu obinrin to bimọ marun-un fun un pa. Akọkọ ni pe Pasitọ Enoch fẹsun agbere kan iyawo rẹ torukọ ẹ n jẹ Patience, o ni obinrin naa n yan ale, bẹẹ lo si tun n fi ogun ja aye oun pẹlu iwa iṣekuṣe to n ṣe kiri.

Ohun keji tawọn eeyan tun fidi ẹ mulẹ, ti wọn ni Pasitọ Ukachukwu funra ẹ sọ, ni pe ko si ero to ni ṣọọṣi oun yii. Wọn lo sọ pe awọn ọmọ ijọ ko tan nnkan, eyi ko si jẹ koun maa rowo na, nitori ko le si nnkan gidi fun pasitọ ti ko ni ero lẹyin, owo gidi kan ki i si lọwọ iru wọn.

Airowo naa yii la gbọ pe o fa a ti Pasitọ Enoch fi fọrọ lọ babalawo kan niluu wọn ti i ṣe Ikọt Abia, ni Akwa Ibom nibẹ. Babalawo yii ni wọn lo sọ fun pasitọ pe to ba le fi iyawo rẹ silẹ fun igbedide ṣọọṣi naa, ero yoo pọ ju yẹẹpẹ ilẹ lọ nibẹ, agbara buruku yoo si tun kun ọwọ rẹ pẹlu, ohun to ba n sọ yoo maa ṣẹ ni.

Ki i ṣe pe ki Enoch fa iyawo ẹ silẹ bẹẹ ni babalawo n wi, o ni ko jẹ kawọn lo o fun awure ọla ni.

Nitori ija to ti wa nilẹ tẹlẹ laarin pasitọ ọhun ati iyawo ẹ, ati ẹsun agbere to fi n kan an, nigba ti ija tun ṣẹlẹ laarin wọn lọsẹ to kọja lọhun-un, Pasitọ Ukachukwu lu obinrin naa kọja aala, nibi to si ti n lu u lo ti ṣubu yẹgẹ, lo ba ku mọ ọkọ rẹ lọwọ.

Ọkunrin yii mọ pe ọran nla loun da bawọn eeyan ba fi le mọ ohun to ṣẹlẹ, lo ba gbẹlẹ koto ninu ọgba ile wọn nibẹ, o si sin obinrin to bimọ marun-un naa fun un sibẹ, o ṣoju furu bii pe kinni kan ko ṣe.

Ọmọ keji ti oloogbe naa bi, to jẹ ọkunrin, lo jẹ kawọn eeyan mọ pe iya awọn ko si laye mọ, o si lọwọ kan baba awọn ninu o. Ọrọ pada di tọlọpaa, wọn wa sile pasitọ naa, nibẹ ni wọn ti ri ibi kan ti wọn sin oku si, wọn beere bo ṣe je lọwọ Pasitọ Ukachukwu, o si jẹwọ pe Patience, iyawo oun, ẹni ogoji ọdun to doloogbe, lo wa ninu saaree naa.

O fi kun un pe ọwọ oun lo ku si nigba tawọn n ja, oun lu u pa a ni.

Awọn ọlọpaa hu oku obinrin naa lọ fun ayẹwo, wọn si mu Pasitọ Enoch lọ satimọle.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom, Odiko Macdon, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹfa, lọwọ ba pasitọ, to si jẹwọ pe niṣe loun luyawo oun pa.

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: