Ọlawale Ajao, Ibadan
O han gbangba pe loootọ ni Jesu fẹran ọmọbinrin kan to n jẹ Jesufẹranmi, pẹlu bi ori ṣe ko o yọ ninu igbekun awọn ajinigbe lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ Kẹta, oṣu Kejila, ọdun yii.
Orukọ ro Jesufẹranmi. Ṣugbọn ko jọ pe bẹẹ lorukọ yoo ro Pasitọ Ọlọrunkọya Akinọla Kọlawọle, ọkan ninu awọn to ji ọmọbinrin yii gbe pẹlu bi ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ṣe tẹ ọkunrin naa, ti CP Adebọwale Williams, ti i ṣe ọga agba ọlọpaa ipinlẹ naa si ti leri pe dandan ni ko jiya to tọ si i labẹ ofin.
B’Ọlọrun yoo ba tilẹ kọya fun Ọlọrunkọya lori iṣẹlẹ yii, ko jọ pe ikọya ọhun yoo ya kiakia, nitori ọjọ marun-un ni pasitọ yii ti lo lahaamọ awọn agbofinro l’Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, boya ni yoo si le jade nibẹ titi ti ile-ẹjọ yoo fi ṣedajọ ẹ. Idajọ si ree, o le ma waye laarin oṣu meji sasiko yii, bẹẹ, wọn ko ti i gbe ẹjọ naa de kootu rara.
Gẹgẹ bi Alukoro funleeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, ṣe fidi ẹ mulẹ lorukọ CP Adebọwale Williams ti i ṣe Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ yii, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 yii, lọkunrin ẹni ọdun mọkandinoọgbọn yii huwa ọdaran naa.
Laduugbo Ọjọọ, n’Ibadan, larufin yii pẹlu awọn ẹgbẹ rẹ nidii iwa ọdaran ti ji ọmọọlọmọ gbe, to si pe ẹgbọn ẹ to wa niluu oyinbo pe ko fi miliọnu mẹfa Naira ranṣẹ si oun bi ko ba fẹ ki oun yinbọn pa aburo ẹ to wa latimọle oun danu.
Ọgbẹni Akinwọle to jẹ baba ọmọ naa lo fiṣẹlẹ ọhun to awọn agbofinro leti. Loju-ẹsẹ si lawọn ọlọpaa to n gbogun ti iṣẹlẹ ijinigbe fọn da sigboro lati doola ẹmi ọmọdebinrin naa.
ALAROYE gbọ pe ilu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, lawọn Ọlọrunkọya gbe Jesufẹranmi pamọ si.
Lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ọdun ta a wa yii lawọn agbofinro ya lu wọn nibuba wọn, ti wọn yọ ọmọbinrin naa ninu ide nibẹ, ti wọn si mu eyi to n jẹ Ọlọrunkọya ninu awọn afurasi ọdaran naa.
Titi ta a fi pari akojọ iroyin yii, inu atimọle awọn ọlọpaa to n gbogun ti iṣẹlẹ ijinigbe (AKS), nipinlẹ Ọyọ lọkunrin ayederu pasitọ naa wa nigba ti iwadii awọn ọlọpaa lori iṣẹlẹ yii, ati akitiyan wọn lati fiya jẹ Ọlọrunkọya ṣi n tẹsiwaju.