Pasitọ ṣeku pa obinrin to ba aajo ọmọ lọ sọdọ rẹ, ladajọ ba ju u sẹwọn gbere l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti 

Ile-ẹjọ giga ilu Ado-Ekiti ti ran Pasitọ Ọlakanye Oni, lẹwọn gbere fun ẹsun iṣeeṣipaayan.

Ẹjọ to ran Pasitọ Ọlakanye lẹwọn yii bẹrẹ loṣu kẹta, ọdun 2017, nigba ti obinrin kan to ti doloogbe bayii, Ọmọwale Gbadamọsi, wa si ṣọọṣi pasitọ yii, iyẹn Palace of Mercy, to wa ni adugbo Matthew, Odo-Ado, l’Ekiti, nitori iṣoro airọmọbi to ni.

Ọgbọn alumọkọroyi ni Pasitọ Oni fi pe obinrin naa wa lati Eko, to loun yoo gbadura fun un, yoo si loyun ayọ. Ṣugbọn nigba ti Ọmọwale de ọdọ pasitọ, niṣe lo lo nnkan fun un ti obinrin naa ko si mọ ibi to wa mọ.

Lẹyin eyi ni pasitọ yii gbe e wọ yara kan, o da aṣọ funfun bo o, o si ba a laṣepọ.

Lẹyin ibaṣepọ naa ni Pasitọ Ọlakanye fi aṣọ funfun nu oju ara obinrin to wa ọmọ wa sọdọ rẹ yii, o si ki kinni kan ti wọn ni kanun ni, bọ ọ loju ara. Awọn kan sọ pe oogun dudu ni pasitọ ki si i labẹ, ki i ṣe kanun rara.

Ki gbogbo eyi too ṣẹlẹ ṣa, ẹgbẹrun mejilelọgọta (52,000) ni Ọlakanye ti gba lọwọ Ọmọwale.

Abajade ohun to ki si i lara naa lo jẹ ki oju abẹ obinrin yii bẹrẹ si i jẹra, ko gbadun mọ nigba to pada siluu Eko, kinni ọhun lo si pada yọri siku fun un.

Iku Ọmọwale di wahala si pasitọ lọrun, ọrọ di tọlọpaa ati kootu, wọn si ti wa lẹnu ẹ latigba naa titi di ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun 2021, ti idajọ waye.

Adajọ Andrew Adesọdun sọ pe gbogbo ẹri awọn ẹlẹrii mẹfa lati ẹka to n gba ile-ẹjọ nimọran (Public prosecution ), lo foju han kedere pe loootọ lo jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Adajọ Adesọdun ni ẹwọn gbere ni ijiya to tọ si Pasitọ Ọlakanye Oni, nitori naa, ko lọọ lo iyooku aye rẹ lẹwọn.

Leave a Reply