Pasitọ Tunde Bakare ti gba fọọmu miliọnu lọna ọgọrun-un Naira, o fẹẹ dupo aarẹ

Olori ijọ Citadel Global Community, Pasitọ Tunde Bakare, naa ti darapọ mọ awọn oludije fun ipo aarẹ ilẹ wa pẹlu bi baba naa ṣe ti gba fọọmu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un miliọnu Naira ninu ẹgbẹ APC.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni Bakare gba fọọmu tiẹ naa naa niluu Abuja. Pẹlu boun naa ṣe jade yii, oun ni ẹni kẹta to ti fifẹ han lati dupo aarẹ lati ipinlẹ Ogun.
Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, lo kọkọ lewaju ninu awọn to fifẹ han. Lẹyin eyi ni gomina ipinlẹ Ogun telẹ, Ibikunle Amosun, naa fi erongba rẹ lati dije han, ko too waa kan Bakare to ṣẹṣẹ gba fọọmu yii.
Bakan naa ni awọn eeyan mi-in naa kaakiri ilẹ Yoruba, ilẹ Ibo ati Oke Ọya ti n gba fọọmu pe awọn naa fẹẹ dupo aarẹ yii.
Ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu yii, ni idibo abẹle ẹgbẹ APC yoo waye, nibi ti wọn yoo ti fa oludije kan kalẹ lorukọ ẹgbẹ naa.

Leave a Reply