Pasitọ wa n ba iyawo mi lo pọ, mi o fẹ ẹ mọ – Johnson

Idowu Akinrẹmi, Ikire

Baale ile kan, Olumuyiwa Johnson, wa si kootu ibilẹ to wa ni Mapo, n’Ibadan, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pe ki kootu naa ya oun atiyawo oun, Ọmọtayọ, nitori pasitọ ijọ awọn pẹlu alagba kan n ba a sun, ile-ẹjọ naa si ṣe bẹẹ gẹlẹ, lẹyin ti wọn ti pe iyawo naa lọpọ igba ti ko si wa.

Ọdun kẹrinlelogun ree tawọn tọkọ-taya yii ti ṣegbeyawo gẹgẹ bi Johnson ṣe wi, o ni ṣugbọn bi Mọtayọ ṣe jẹ alagbere lo tun n lepa ẹmi oun. Ọmọ meji lo ni awọn bi.

Olumuyiwa to n gbe lagbegbe Ẹlẹta, niluu Ibadan, ṣalaye pe iyalẹnu lo jẹ pe iyawo oun tun le maa yan pasitọ ati alagba ijọ awọn lale pẹlu bo ṣe ti pẹ to ti awọn ti n ba ifẹ awọn bọ. O ni latigba toun si ti ri aṣiri iwa agbere rẹ yii lo ti n lepa ẹmi oun.

Johnson ni gbogbo igba ni iyawo oun maa n ni oun n lọ fun Imọran ati ẹ̀bẹ̀ adura lọdọ awọn pasitọ naa, aṣe o n lọọ gba kinni wọn sara ni.

O sọ fun kootu pe bẹẹ, ọpọ igba lawọn alagba yii maa n bawọn yanju ija, aṣe wọn n ba iyawo oun sun.

O ni lẹyin ti aṣiri naa tu soun lọwọ loun pinnu lati ma lọ si ṣọọṣi naa mọ.

Ọkunrin yii tun fẹsun kan Ọmọtayọ pe nina lo maa n na owo ileewe awọn ọmọ nigba toun ba ni ko lọọ ba wọn san an.

Ọmọtayọ ko si nile-ẹjọ lati fesi sawọn ẹsun naa, ile-ẹjọ si ti pe e titi, ko wa. Iyẹn ni Aarẹ Ademọla Ọdunade ṣe tu igbeyawo naa ka lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, to si paṣẹ pe kawọn ọmọ meji to da wọn pọ wa lọdọ Johnson ti i ṣe baba wọn.

Leave a Reply