Pastor Temitọpẹ Joshua, oludasilẹ Ṣọọṣi Synagogue, ku lojiji

Faith Adebọla, Eko 

Gbajugbaja ajihinrere oniwaasu agbaye nni, to tun jẹ oludasilẹ ati adari ijọ Synagogue, Pasitọ Temitọpẹ Balogun Joshua, ti doloogbe.

Ba a ṣe gbọ, alẹ ọjọ Abamẹta, Satide yii, lẹyin to pari isin alẹ kan to waye ninu ṣọọṣi rẹ, Synagogue Church of All Nations, to wa lagbegbe Ikọtun, niluu Eko, wọn lọkunrin naa sọ pe o rẹ oun diẹ, oun fẹẹ lọọ sun, bẹẹ ni ko ji saye mọ, wọn si ti gbe oku rẹ lọ si mọṣuari ọsibitu Jẹnẹra Isọlọ, nipinlẹ Eko.

Ko ti i sẹni to le sọ pato ohun to ṣokunfa iku airotẹlẹ yii, tori o ku ọjọ mẹfa pere ti ọkunrin naa yoo ṣayẹyẹ ọjọ-ibi rẹ, ti eto si ti n lọ loriṣiiriṣii lati ṣayẹyẹ alarinrin fun un niṣẹlẹ yii waye.

Ẹni ọdun mẹtadinlọgọta (57) ni, ọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 1963 ni wọn bi i.

Aipẹ yii lọkunrin naa kọ awọn ọrọ sori ikanni fesibuuku rẹ lori atẹ ayelujara nipa ọjọọbi rẹ to n bọ lọna naa, o kọ ọ sibẹ pe:

“Bi nnkan ṣe ri lasiko yii, ẹ le ti ṣakiyesi pe ko ni i rọrun fun mi lati ṣayẹyẹ ọjọọbi mi to sun mọle yii, nitori ilu ko fara rọ. Ọpọ awọn eeyan ti iba waa ba mi ṣayẹyẹ ko ni i le wa tori ọrọ aabo ti ko dara to loril-ede wa ati kari aye. A ri ibẹru wọn aniyan ọkan wọn. Mo mọ ọn lara bo ṣe dun wọn to, mo si mọ ero-ọkan wọn pẹlu. Tori naa, ẹ jẹ ka ya ọjọ yii sọtọ fun aawẹ ati adura. Ka ma si gbagbe awọn alaini ati mẹkunnu.”

A gbọ pe lati bii ọjọ meji ṣaaju iku rẹ ni ara baba naa ko ti ya daadaa, ṣugbọn aisan naa ko da a dubulẹ, ko si sẹni to le ro pe boya tọlọjọ ni.

Leave a Reply