Pasuma fọmọ rẹ f’ọkọ, o ni Ayọ̀ nla ni foun

Ọkan pataki ninu awọn ilu mo-ọn-ka onifuji ile wa nni, Àlàájì Alabi Pasuma ko le pa idunnu rẹ mọra pẹlu bi ọmọ ẹ obinrin, Oyindamọla, ṣe ṣegbeyawo pẹlu ọkọ rẹ, Ọlajuwọn, ni Ọjọ́bọ̀, Tọsidee, ọsẹ yii.
Níṣẹ́ ni baba iyawo, ìyẹn Pasuma ko sinu agbada ofi nla to rẹwa, to si fa ọmọ rẹ obinrin yii toun naa wa ninu aṣọ igbeyawo lọwọ.
Ẹni ba gẹsin ninu Pasuma ti wọn tun mọ si ọba ọrobọkibọ yii ko ni i kọsẹ, sẹnkẹn ni inu rẹ n dun, bọ se fa ọmọ rẹ lọwọ, to n mu un lọ sibi ti wọn ti fẹ́ẹ́ so wọn pó nilana Musulumi.

 


Baba iyawo yii sọ pe ”Adun ati ìpèníjà to wa ninu ki eeyan jẹ obi naa ni pe ko si bi obi ṣe le di ọmọ rẹ lọwọ mu to pe ko ma lọ, to ba ya, yoo ju ọwọ rẹ silẹ naa ni pe ko maa lọ sile ọkọ.
”Inu mi dun lónìí, ayọ mi si kun pe ọmọ mi kekere igba kan lo ti waa dagba, to n ṣegbeyawo lónìí, ti mo di lọwọ mu ti mo n mu lọ sini to ti fẹ́ẹ́ ṣe Nikah. O je ohun iwuri fun mi.
Mo gbagbọ pe ki i ṣe pe igbeyawo yin yoo tọjọ nikan, ṣùgbọ́n yoo jẹ eri fun awọn to yi yin ka pe ifẹ dun, ifẹ daa, o si maa n fara da ohun gbogbo.”

Leave a Reply