Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣèyí Makinde, tí ṣiwaju awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP l’Ondo lati ta ko iyansipo Ọjọgbọn Eyitọpẹ Ogungbenro Ogunbọdẹde gẹgẹ bii olori ajọ INEC ti yoo dari eto idibo to maa waye ni Satide, ọjọ Abamẹta, yii.
Ohun ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP sọ ni pe olori awọn oṣiṣẹ eleto idibo tí yoo mojuto bi idibo ṣe maa waye, to tun duro gẹgẹ bii ẹni to maa kede ẹni to jawe olubori, ọmọ ilu kan naa loun ati Rotimi Akeredolu.
Ṣeyi Makinde to jẹ alaga fun ipolongo ibo Eyitayọ Jẹgẹdẹ to n dije labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ti sọ pe awọn eeyan ipinlẹ Ondo ko le ri esi ibo gidi ti ọga agba Yunifasiti Ọbafẹmi Awolọwọ yii, Ọjọgbọn Ogunbọdẹde, ba fi le dari eto idibo ọhun.
Ilu Akurẹ lawọn Ṣeyi Makinde ti sọrọ yii, bẹẹ ni inu n bí wọn gidigidi.
Wọn ti sọ pe lọdọ ajọ agbaye gan-an lawọn yoo pariwo ojooro buruku ti ajo INEC atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC fẹẹ ṣe fawọn yìí lọ, bẹẹ lawọn ko si ni i gba ki wọn fi ojooro dun awọn eeyan ipinlẹ Ondo leto ibo gidi.
Ẹgbẹ yii ti sọ pe ohun tawọn fẹ bayii ni ki ajọ INEC paarọ ọkunrin naa, ki wọn si wọ yunifasiti mi–in lọ lati lọọ mu ẹni tí ko ni i ni ohun kankan i ṣe pẹlu ipinlẹ Ondo, tabi ẹgbẹ oṣelu kankan.
Bakan naa lo rọ awọn ẹsọ agbofinro pe ki wọn ma ṣe lọwọ si madaru lasiko ibo ọhun, bẹẹ lo ke si awọn ajọ agbaye naa lati foju si ibo to maa waye lọjọ Abamẹta yii, paapaa bi ẹgbẹ oṣelu APC ṣe n wa gbogbo ọna lati da nnkan ru mọ awọn lọwọ.