Ẹgbẹ PDP Ekiti lawọn ko ni i kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ to n bọ lọna

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ẹgbẹ Ọlọnburẹla, PDP, nipinlẹ Ekiti ti kede pe ọmọ ẹgbẹ awọn kankan ko ni i kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ to n bọ lọna nipinlẹ naa.

Ohun to fa eyi gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ni pe ẹgbẹ APC ti kọ esi idibo ti ko ti i waye naa, ti wọn si ti kede rẹ laarin ara wọn ko too di ọjọ idibo naa.

Ninu abajade ipade Igbimọ alabẹsekele ẹgbẹ naa ti wọn ṣe ni Ọjọbọ, Tọside, ọsẹ to kọja, ni ẹgbẹ naa, ti Ọgbẹni Lanre Ọmọlaṣẹ jẹ alaga wọn, ti sọ pe wọn ko gbọdọ kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ naa.

Lara awijare wọn ni pe APC ko kunju oṣuwọn lati ṣeto idibo ti ko ni i ni magomago ninu, tabi ti yoo lọ ni irọwọrọsẹ lai mu ipaniyan dani.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro fun eto iroyin ẹgbẹ  PDP nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Raphael Adeyanju, fi sọwọ sawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, lo ti juwe ẹgbẹ APC gẹgẹ bii ooṣa to maa n gba ẹjẹ, lai fi ti pe ọmọ ẹgbẹ wọn tabi ẹgbẹ alatako ni ṣe.

Adeyanju tun ṣalaye pe ajọ eleto idibo ipinlẹ naa, (Ekiti State Independent Electoral Commission SIEC), kọ lati gbe igbesẹ to yẹ labẹ ofin pẹlu bi wọn ṣe kọ lati sọ ọjọ ti eto idibo naa yoo waye fun awọn ẹgbẹ oṣelu yooku.

Ninu awijare tirẹ, Alukoro fun eto iroyin ẹgbẹ APC l’Ekiti, Ọgbẹni Ade Ajayi, sọ pe igbesẹ ẹgbẹ alatako lati ma kopa ninu eto idibo ijọba ibilẹ naa fi han pe inu wọn dun si aṣeyọri ti Gomina Kayọde Fayẹmi n ṣe, nitori o ti ṣiṣẹ takuntakun nipinlẹ naa

Ajayi ni idunnu ni yoo jẹ fun ẹgbẹ awọn ti ẹgbẹ alatako ba kopa ninu eto idibo ọhun, wọn yoo le mọ bi wọn ṣe gbajumọ to nipinlẹ Ekiti

O fi kun un pe yatọ si ẹgbẹ PDP, ẹgbẹ oṣelu mẹẹẹdogun lo ti fifẹ han lati kopa ninu eto idibo ọhun.

“Tẹ o ba gbagbe, lasiko ti ẹgbẹ oṣelu APC ṣe idibo abẹle wọn ni rogbodiyan ati ipaniyan waye, to si fa iku ọdọmọkunrin kan.

Leave a Reply