PDP ni ki Buhari fi ọrọ ti Aarẹ ilẹ Amẹrika ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan sọ kọgbọn

Aderohunmu Kazeem

Ẹgbẹ oṣelu PDP ti ke si Aarẹ MuHhammadu Buhari ko kẹkọọ latara ohun ti Joe Biden, Aarẹ tuntun nilẹ Amẹrika sọ, ko si yago fun awọn iwa ti ko le ko oriire kankan ba Naijiria.

Ninu ọrọ ikini ku oriire ti Alukoro fun ẹgbẹ oṣelu PDP, Kọla Ọlọgbọndiyan, kọ lo ti sọ pe o ṣe pataki ki Aarẹ Muhammadu Buhari sagbeyewọ ọrọ ti Joe Biden sọ nipa bi awọn to wa nipo oṣelu ṣe maa n lo ipo wọn fi dun awọn to sun mọ wọn nikan ninu, eyi to le sakoba fun idagbasoke awujọ.

O ni irufẹ iwa yii ati bi awọn agbegbe kan ko ṣe ri anfaani ijọba jẹ wa ninu ijọba Buhari. Bẹẹ lo fi kun un pe asiko niyi fun un lati jawọ ninu ẹ, ko si wa bi Naijiria yoo ṣe bọ lọwọ iṣẹ ati ebi.

Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu PDP ki Joe Biden ku oriire ibo to gbe e wọle ọhun, eyi to fun un lanfaani lati di Aarẹ kẹrindinlaaadọta nilẹ Amẹrika.

Wọn ni ẹkọ nla to yẹ ki eeyan kọ lori ọrọ ibo to gbe Joe Biden wọle l’Amẹrika ni pe lọdọ araalu gan-an ni eto iṣelu wa, nitori pe ijọba ti wọn ko ba ti fẹ mọ, agbara idibo ti wọn ni ni wọn yoo fi yọ ọ danu lọgan.

Wọn ti waa rọ Biden, ko lo ipo ẹ tuntun yii lati fi wa alaafia, irẹpo ati iṣọkan si aarin awọn orilẹ-ede lagbaye.

Bẹẹ ni wọn tun gba a niyanju ko fa awọn orilẹ-ede to ṣẹṣẹ n dagba bọ mọra ni Afrika atawọn ibomi-in kaakiri agbaye lori eto ọrọ aje.

Leave a Reply