PDP yan igbimọ alaamojuto tuntun fun ipinlẹ Eko

Faith Adebọla, Eko

Latari bi eto idibo abẹle to yẹ ko waye loṣu kẹwaa ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) nipinlẹ Eko ṣe fori ṣanpọn, igbimọ amuṣẹṣe apapọ (National Working Committee) ẹgbẹ naa ti yan igbimọ alaamojuto ti yoo maa dari ẹgbẹ naa nipilẹ ọhun fun oṣu mẹta.

Ninu lẹta kan ti ẹgbẹ PDP fi lede lọjọ Wẹsidee, l’Abuja, eyi ti Akọwe apapọ ẹgbẹ naa, Ajagun-fẹyinti Austin Akobundu, buwọ lu, Ẹnjinnia Julius Akinṣọla ni wọn fi ṣe Alaga igbimọ ẹlẹni mẹsan-an naa, Ọnarebu Ade Adeniyi si ni Akọwe rẹ.

Awọn ọmọ igbimọ yooku ni Ọgbẹni Ademọla Oyede, Dokita Babs Akinlolu, Ọgbẹni Nuru Abiọdun Lawal, Alaaja Ọlọrunkẹmi Babatunde,

Oloye Alani Ige, Abilekọ Ọlabisi Ọdunsi ati Alaaji Bọde Ọladẹhinde.

Wọn ni igbimọ kiateka yii lo maa tukọ ẹgbẹ naa l’Ekoo lati oṣu kọkanla yii titi di oṣu keji, ọdun to n bọ, tawọn maa fi dibo yan igbimọ alakooso ẹgbẹ gidi.

Leave a Reply