PDP yoo ṣeto idibo abẹle funpo aarẹ ninu oṣu karun-un

Adewumi Adegoke

Ti gbogbo nnkan ba lọ bi wọn ti ṣeto rẹ, opin oṣu Karun-un, ọdun yii, ni eto idibo abẹle oṣelu PDP yoo waye, nibi ti wọn yoo ti yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ wọn ninu eto idibo aarẹ ati ti gomina ti yoo waye lọdun to n bọ.

Ẹgbẹ naa ti gbe igbimọ ẹlẹni mẹtadinlọgbọn kan dide ti yoo ri si bi wọn yoo ṣe pin awọn ipo naa laarin awọn agbegbe kọọkan nilẹ wa.

Miliọnu lọna ogoji ni wọn yoo ta fọọmu fun awọn ti yoo dije dupo aarẹ, nigba ti awọn ti yoo dije dupo gomina yoo ra fọọmu tiwọn ni miliọnu mọkanlelogun Naira.

Ẹgbẹrun lọna ẹgbẹta (600,000) ni awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin ipinlẹ yoo san fun fọọmu tiwọn. Awọn ileegbimọ aṣoju-ṣofin yoo san miliọnu meji ataabọ (2.5m), nigba ti awọn to fẹẹ dije dupo aṣofin agba yoo san miliọnu mẹta ataabọ.

Bakan naa ni awọn ọmọ igbimọ ẹgbẹ fọwọ si i pe idaji owo naa ni ki awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn ba wa laarin ọdun mẹẹẹdọgbọn si ọgbọn (27-30yrs) san fun gbogbo awọn ipo naa ti wọn ba nifẹẹ si.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni wọn fẹnu ko si pe ki tita awọn fọọmu naa bẹrẹ, ti yoo si wa sopin ni ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Alaga ẹgbẹ naa, Sẹnetọ Iyorchia Ayu, rọ gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ lati wa ni iṣọkan, ki wọn le baa ṣe aṣeyọri, ki ẹgbẹ naa si le rọwọ mu ninu eto idibo gomina ti yoo waye nipinlẹ Ọṣun ati Ekiti, ati ti aarẹ lapapọ.

Leave a Reply