Pẹlu bawọn ọlọpaa ṣe n wa a, Portable olorin ṣegbeyawo pẹlu iya ọmọ ẹ

Monisọla Saka

Idunnu nla lo ṣubu lu ayọ fun gbajugbaja olorin asiko to kọ orin Zaa zuh nni, Habeebullah Okikiọla, ti wọn n pe ni Portable. Pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe ni awọn n wa ọmọkunrin naa, eyi ko di i lọwọ lati ṣe igbeyawo pẹlu obinrin to bimọ fun un, Zainab Badmus, lọjọ ti wọn n ṣe ikomọjade ọmọ wọn keji.
Ninu fidio kan to gba ori afẹfẹ kan ni Portable ti gbe ọmọkunrin ti wọn ṣẹṣẹ bi naa lọwọ, lẹyin ọpọlọpọ waasi ni awọn aafaa to wa nikalẹ so yigi wọn, wọn ṣadura fun tọkọ-taya, bẹẹ ni wọn bẹ Ọlọrun fun Portable pe ki ogo ẹ to n tan ma ṣe wọ ookun lojiji.
Ariwo nla sọ nigba ti ọkunrin olorin yii bẹrẹ si i rọjo owo le iyawo ẹ lori. Lẹyin eyi ni tọkọ-taya naa fi oruka ifẹ si ara wọn lọwọ, ti awọn aafaa si n sọ bi Portable ṣe nifẹẹ obinrin naa to ninu fidio ọhun. Foonu olowo nla to gba igboro kan bayii ti wọn n pe ni iPhone 13 pro meji lo wa lọwọ ẹ, o ni oun loun ni ọkan, ekeji yoo si jẹ ti ololufẹ oun, Zaynab.
Lọsẹ ta a wa yii ni ileeṣẹ ọlọpaa kede pe awọn n wa Portable lori ẹsun pe o ran awọn kan lati fiya jẹ ọkan ninu awọn to ṣẹ ẹ, eyi tawọn agbofinro ni o lodi sofin. Latari eyi ni wọn ṣe ni ko fẹsẹ ara ẹ rin wa si agọ wọn, sibẹ, ọmọkunrin yii ko jẹ ki eleyii di oun lọwọ lati ṣe ajọyọ oriire ikomọ ati igbeyawo yii.
Awọn ololufẹ Portable atawọn ti wọn n gba tiẹ lori ẹrọ ayelujara naa ba a yọ, wọn ki i ku oriire tọmọ tuntun ati igbeyawo, bẹẹ lawọn mi-in n pe akiyesi awọn eeyan si bi oju Zaynab to jẹ iyawo tuntun ọkunrin olorin yii ṣe faro, nigba ti awọn kan n sọ pe agidi ti portable fi fi oruka si i lọwọ lo fa a, nitori aibalẹ ara ẹ. Awọn mi-in ni o ṣee ṣe ki o ti ya ọmọbinrin naa nigbaaju laaarọ kutu ọjọ naa ki inawo too bẹrẹ.

Leave a Reply