Pẹlu bi awọn ti korona mu ṣe n pọ si i, awọn aṣofin Eko ni ki ijoba bẹrẹ eto ilanilọyẹ faraalu

Faith Adebọla, Eko

Ile-igbimọ aṣofin Eko ti ke si Gomina ipinlẹ naa, Babajide Sanwo-Olu, lati tete bẹrẹ ipolongo ati ilanilọyẹ lakọtun nipa arun aṣekupani koronafairọọsi to ti bẹrẹ si i gberu nipinlẹ naa. Bakan naa ni wọn ke si kọmiṣanna feto ilera, Dokita Akin Abayọmi, lati waa ṣalaye awọn igbeṣẹ tijọba n gbe lati ri oogun korona ti wọn lawọn orileede oke-okun kan ti ṣawari ẹ.

Nibi apero wọn to waye nileegbimọ ọhun, l’Alausa, Ikẹja, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee yii, ni wọn ti sọrọ naa.

Olori wọn, Ọnarebu Mudaṣiru Ọbasa, to tẹ pẹpẹ ọrọ yii siwaju awọn ẹlẹgbẹ rẹ ni pẹlu bi iye eeyan to lugbadi arun naa tun ṣe n lọ soke lẹnu ọjọ mẹta yii, leyii ti ko yọ Gomina Sanwo-Olu funra ẹ silẹ, afi ki wọn tete ṣekilọ faraalu nipa ewu ti akoran le mu wa.

Awọn aṣofin naa ni ki gomina ṣeto fun Kọmiṣanna lori eto iroyin, Gbenga Ọmọtọshọ, lati bẹrẹ ikede to rinlẹ kawọn eeyan le kiyesara nipa arun buruku naa, paapaa lasiko yii tawọn ọmọleewe ṣi n kawe lọwọ, tawọn eeyan si ti n dana ariya loriṣiiriṣii.

Wọn tun ni o ṣe pataki ki Abayọmi yọju si igbimọ alabẹ-ṣekele ile aṣofin naa nipa ilera .

Ọnarebu Adebisi Yusuf sọ pe ko ni i daa ti ofin konilegbele ba tun waye nipinlẹ Eko, tori ẹ lo fi yẹ ki wọn gbe igbesẹ lati dena ohun to tun le fa inira ati ijaya bayii.

Leave a Reply