Pẹlu eto tijọba ṣe, ko sẹni to le yọ wọle lati awọn ẹnuubode orileede yii mọ – Arẹgbẹṣọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Minisita fun ọrọ abẹle nilẹ wa, Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla, ti ṣalaye pe pẹlu igbesẹ iforukọsilẹ tijọba apapọ gbe bayii, ko si anfaani fun ẹnikẹni lati yọ wọ orileede yii latẹnuboode wa mọ.

Arẹgbẹṣọla sọrọ naa nibi eto kan niluu Ileṣa lopin ọsẹ to kọja. O ni o ti pọn dandan lati bẹrẹ si i mọ bi awọn eeyan ṣe n wọle, ti wọn si n jade, latawọn ẹnubode wa kaakiri, idi niyi ti wọn fi bẹrẹ ohun ti wọn pe ni Migration Information Data Analysis System.

O fi kun ọrọ rẹ pe eto iforukọsilẹ naa ti bẹrẹ ni ẹnubode ilẹ wa mẹrẹẹrin tijọba apapọ paṣẹ pe ko di ṣiṣi laipẹ yii, wọn yoo gba orukọ, fọto, adirẹsi atawọn nnkan mi-in nipa ẹnikẹni to ba wọle tabi jade.

Arẹgbẹṣọla sọ pe pẹlu bijọba ṣe si awọn ẹnubode ilẹ naa, ofin ṣi de kiko awọn nnkan bii irẹsi, tọki, awọn nnkan ija oloro pẹlu awọn nnkan mi-in wọle.

Ni ti ipinlẹ Ọṣun, Arẹgbẹṣọla ṣalaye pe ko si ija kankan laarin oun ati Gomina Gboyega Oyetọla. O ni digbi lẹgbẹ oṣelu APC wa, ati pe ẹgbẹ naa tun ti ṣetan fun idibo to ba n bọ l’Ọṣun.

Leave a Reply