Pẹlu ofin konilegbele, awọn ọdọ yari, wọn ko kuro ni Lekki ati Alausa

O jọ pe awọn ọdọ ile wa to n ṣewọde lori SARS ko mu ọrọ naa ni kekere o, beẹ ni wọn ko si kọ ohun ti ọrọ naa le da pẹlu bi wọn ṣe kọ ti wọn ko kuro ni ọgangan ibi ti wọn ti n ṣe iwọde wọn ni agbegbe Lẹkki ati Alausa, niluu Eko. Titi di asiko ta an ko iroyin yii jọ ni awọn oluwọde naa wa nibe. Niṣe ni wọn to ara wọn lọwọọwo kalẹ nibe ni Lẹkki. Awọn to jokoo sileẹle jokoo, awọn to sun sile naa ṣe bẹẹ.

Eyi to ya awọn eeyan lẹnu ni ti awọn oluwọde to wa ni Alausa. Awọn ọlọpaa ati ṣoja gba agbegbe naa kọja, ṣugbọn wọn ko tilẹ de ọdọ awọn oluwọde yii rara, wọn kan kọja lọ ni tiwọn ni.

Awọn ọdọ to n ṣewọde yii paapaa lo n palẹ oju ọna mọ fun mọto awọn olọpaa naa lati kọja, ti wọn si saaju wọn ki wọn le rọna lọ ki awọn janduku ma baa da wọn lọna tabi di wọn lọwọ.

Leave a Reply