Peter Obi ko le wọle sipo aarẹ ni 2023, PDP lawọn Igbo maa dibo fun – Ekweremadu

Faith Adebọla
Igbakeji olori awọn aṣofin tẹlẹ to n ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Iwọ-Oorun Enugu, nipinlẹ Enugu, Ọgbẹni Ike Ekweremadu, ti la a mọlẹ pe bi gomina ipinlẹ Anambra tẹle, to tun jẹ oludije funpo aarẹ lọdun 2023 labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, Ọgbẹni Peter Obi, yoo ba wọle ibo, ki i ṣe ti ọdun 2023 to n bọ lọna yii, tori o da oun loju pe ọkunrin naa ko le jawe olubori rara, ati pe ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party lawọn eeyan ẹya Igbo maa dibo wọn fun.
Ekweremadu sọrọ yii l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹfa yii, niluu rẹ, lasiko to n dahun ibeere tawọn oniroyin bi i.
“Guusu/Ila-Oorun ni mo ti wa, ẹya Igbo pọnbele ni mi. Ẹgbẹ oṣelu PDP lawọn Igbo maa dibo fun, iyẹn da mi loju tadaa, mo le fọwọ sọya daadaa, ohun ti mo mọ ni.
“Ko sirọ nibẹ pe ọmọ wa ni Peter Obi, eeyan daadaa si ni, ṣugbọn a gbọdọ mọ bi nnkan ṣe n lọ. Ibeere to yẹ ka bi ara wa ni pe, ṣe Peter Obi le jawe olubori ibo sipo aarẹ. Ṣe awọn eeyan wa le gba lati diju mọri ki wọn si fi ibo wọn ṣofo ni? Ṣe a le yan lati fi ọna silẹ ka mori le’gbo tori awawi ati imọlara wa ni? Ṣe a le mọ-ọn-mọ ṣe ipinnu to maa ṣakoba fun awa funra wa ati awọn ọmọ wa, atawọn ọmọọmọ wa lẹyinwa ọla ni? Idahun ni pe ‘Rara, a o le ṣe bẹẹ’.
“Tori, a o tiẹ le gbidanwo lati ṣe nnkan to le mu wa tika abamọ bọnu lọjọ iwaju rara. Loootọ, Peter kunju oṣuwọn daadaa o, ṣugbọn ibo ọtẹ yii ki i ṣe tiẹ, awọn igbesẹ to si yẹ ko gbe ṣi wa nilẹ.”
Bẹẹ ni eekan ẹgbẹ oṣelu PDP naa sọ.

Leave a Reply