Jọkẹ Amọri
Nnkan n ṣenuure lọwọlọwọ fun oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi. Ọkunrin naa lo n lewaju, to si ni ibo to pọ ju ninu awọn ibo ti wọn ti ka ni ipinlẹ Plateau, ti olu ilu rẹ wa ni Jos.
Yatọ si pe o ni ibo to pọ ju lọ, ijọba ibilẹ mọkanla lo ti rọwọ mu, to si ti ta awọn ẹgbẹ rẹ ti wọn jọ n dije yọ ninu ijọba ibilẹ mẹtadinlogun to wa nipinlẹ naa, gẹgẹ bi esi idibo tajọ to n mojuto ti ipinlẹ naa ka.
Ni ti oludije sipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ijọba ibilẹ meji pere lo ti yege, nigba ti alatako rẹ ninu ẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar, mu ijọba ibilẹ kan pere.
Ipinlẹ Plateau yii ni ọga agba fun eto ipolongo Aṣiwaju Bọla Tinubu, Simeon Lalong, ti wa.