Peter Obi wọle ni Delta, Abuja

 Adewumi Adegoke

Nigba ti wọn ka ibo aarẹ nipinlẹ Delta, oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi, lo jawe olubori. Ninu esi ibo naa ti olusakoso ibo ọhun funpinlẹ naa, Ọjọgbọn Owunari Georgewill, ka jade lo ti kede pe gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ naa lo jawe olubori pẹlu ibo ẹgbẹrun lọna ọjilelọọọdunrun ati ẹyọ kan o le diẹ (341,866), nigba ti ẹni to ṣe ipo keji, iyẹn oludije fun ẹgbẹ PDP, Atiku Abubakar, ni ibo ẹgbẹrun lọna ọkanlelọgọjọ ati diẹ ( (161,600).

Ẹgbẹ APC lo wa ni ipo kẹta pẹlu ibo ẹgbẹrun lọna aadọrun-un ati diẹ (90,183).

Ijọba ibilẹ mejidinlogun ni ẹgbẹ oṣelu Labour ti rọwọ mu, nigba ti PDP moke ni ijọba ibilẹ meje.

Bakan naa lọrọ ri lolu ilu ilẹ wa to wa ni Abuja. Ẹgbẹ oṣelu Labour naa lo jawe olubori nibẹ. Ninu esi idibo ti oluṣekokaari idibo naa ka, ẹgbẹrun lọna igba ati mọkanlelọgọrin o le diẹ (281, 717), ni Obi ni. Ẹgbẹ oṣelu APC to wa ni ipo keji ni ibo ẹgbẹrun lọna aadọrin ati meji le diẹ (90, 902). Ibo ẹgbẹrun mẹrinlelaaadọrin ati diẹ (79,199), ni ẹgbẹ PDP to wa ni ipo kẹta ni ni tiwọn.

Ninu ijọba ibilẹ mẹfa to wa nibẹ, mẹrin ni ẹgbẹ oṣelu Labour mu, nigba ti APC mu meji.

Leave a Reply